You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Iyabo Ojo: Yomi Fabiyi ní títọrọ àforíjì kìí se ìwà ojo tàbí èèyàn yẹpẹrẹ
Gbajugbaja oṣere tiata Yomi Fabiyi ti ni, ti eniyan ba tọrọ aforiji tabi bẹbẹ fun nnkan ko tumọ si pe eniyan n se ojo tabi ailagbara.
Ninu ọrọ to kọ soju opo Instgagram rẹ pe oun ki lo awọn ọrọ to n pẹtu si aawọ, bi "Ma binu" "Jọ̀wọ́" tabi Ẹ seun ni ilokulo, sùgbọ́n lilo rẹ maa n waye ni asiko to tọ.
Fabiyi ni niwọn igba to jẹ pe biba ara ẹni gbe igbe aye alafia ṣe pataki fun iwa ọmọluabi nitori naa lasiko ti o ba to ni oun maa n lo ki alafia le jọba.
- Jẹ́jẹ́ ni Iyabo Ojo jókòó, èmi ni mo pè é sí ọ̀rọ̀ Baba Ijesha - Lola Alao
- Yomi Fabiyi, ìtíjú ńlá gbáà lo jẹ́ lórí fíímú ''Oko Iyabo'' tóo gbé jáde - Mercy Aigbe
- Yomi Fabiyi ṣe fíìmù lórí ọ̀rọ̀ Baba Ijesha, Iyabo ló dá lé lórí
- "Odeeshi"! Baba Ijesha, Yomi Fabiyi àti gbogbo àwọn tó fẹ́ pa mi, èèyàn lásán niyín o - Iyabo Ojo
- Àbọ̀ wá bá ni ọ̀rọ̀ Iyabo Ojo àti Yomi Fabiyi lórí ọ̀rọ̀ bàbá Ijẹsha - Damola Olatunji, ẹgbẹ́ TAMPAN
- Ẹni tí inú bá ń bí lórí fíìmù Oko Iyabo, le gba iléẹjọ́ lọ - Yomi Fabiyi
Fabiyi lasiko to n la awọn ololufẹ rẹ lori ayelujara lọyẹ, lo fi kun pe ọrọ mẹta pataki lo yẹ ki obi fi kọ ọmọ wọn, nitori eyi ṣe koko fun ibaraẹnigbepọ to mu alafia dani.
"Ó jẹ nnkan ti ọmọ kọọkan gbọdọ mọ bi o ṣe n dagba, ki o si mọ pataki rẹ pẹlu.
Ní gbogbo igba ti mo ba ti n ro Alafia saaju asiko yii ati lọwọlọwọ tabi ni ọjọ iwaju, mo maa n lo ọrọ yìí, kìí ṣe nitori pe mó n sojo tabi nitori pe ẹru n ba mi.
Gbajugbaja osere naa tun ṣalaye pe, ti eniyan ba sọ ọrọ yii ko tumọ si pe ki awọn eniyan maa fi anfani naa yọ suti ete si ẹni to sọ tabi ki wọn jẹ ki ẹni naa maa ro pe eniyan yẹpẹrẹ ni oun.
" Bi ẹnikẹni ba lo awọn ọrọ yìí fun ọ, maa ma ri ara rẹ bi ẹni pe o dara tabi tobi ju ẹni naa lọ, eyi le mu ki o sọ iwa ọmọluabi rẹ nu.
Kìí ṣe gbogbo ọrọ ni eniyan n lo gbele odiwọn ayelujara, o ṣe pataki lati ma huwa afi ọmọniyan ṣe.
Amọ Iyabo Ojo ko tii fesi pada lori isẹlẹ naa.