Baba Ijesha: Iyabo Ojo àti Nkechi Blessing gbà alàáfíà láàyè

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Oṣerebinrin, Iyabo Ojo ti tọrọ aforiji lọwọ awọn adari ẹgbẹ awọn oṣere lorilẹede Naijiria, TAMPAN, lori iṣẹlẹ itahunsi ara ẹni to waye laarin wọn.

Iyabo Ojo ni oun ati akẹgbẹ oun Nkechi Blessing Sunday ti tọrọ aforiji lọwọ ẹgbẹ, ki wọn dariji awọn.

Eyi ko ṣẹyin bi ẹgbẹ TAMPAN ṣe paṣẹ fun gbogbo awọn oludari ere ni Nollywood lati kẹyin si oserebinrin mejeeji.

Wọn ni wọn ko gbọdọ kopa ninu ere kankan ti Iyabo Ojo ati Nkechi Blessing ba fẹ gbe yade nitori wọn ba akẹgbẹ wọn ja lori ọrọ Baba Ijesha lori ẹrọ ayelujara.

Ninu ọrọ to kọ si oju opo Instagram rẹ ni Iyabo ti sọ wi pe 'mọ dupẹ lọwọ Esabod, ki agba yin dalẹ, ẹ ku aduroti.'

'Ni akọkọ ni mọ dupe lọwọ Ọlọrun, alaanu to n duro ti emi ati ẹbi mi ni gbogbo igba, gbogbo ọjọ aye mi ni emi yoo fi ma a dupẹ ni ọwọ Ọlọrun.'

'Mọ fẹ fi asiko yii dupẹ lọwọ awọn alatilẹyin mi nitori ifẹ ti wọn ni si mi ati bi wọn ṣe duro ti mi… mi o ni ko iyan yin kere lailai'

'Bakan naa ni mo dupẹ lọwọ ọga mi ati aarẹ ẹgbẹ TAMPAN, Mr Latin, ẹ ṣeun sir.'

'Ẹyin baba wa nla nla, Adebayo Salami, Jide Kosoko, Yinka Quadri, emi ati Nkechi Blessing tọrọ aforiji lọwọ yin, nitori amu yin binu. '

'Agba ni yin, a si bọwọ fun yin, a dupẹ lọwọ yin fun aduroti yin.'

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Iyabo Ojo, Nkechi Blessing, ẹ ma binu si ẹgbẹ TAMPAN - Mr Latin

Aarẹ ẹgbẹ awọn oṣere lorilẹede Naijiria, TAMPAN, Bolaji Amusan ti gbogbo eniyan mọ si Mr Latin ti tọrọ idariji lọwọ Iyabo Ojo ati Nkechi Blessing fun ọrọ kubakugbe ti Jide Kosoko sọ si wọn.

Ninu fidio ti Iyabo Ojo fi si oju opo Instagram rẹ ni Mr Latin ti bẹbẹ nitori Jide Kosoko pẹlu ọrọ to sọ lati ba inu wọn jẹ.

Ọrọ ti Jide Kosoko sọ nipe oun yoo fi iya jẹ Iyabo Ojo, ti oun yoo si di gbogbo ọna mọ ọna ati jeun rẹ.

Amọ, Latin ni eeyan daadaa ni Jide Kosoko to kan sọ ọrọ ibinu lasan ni.

'Ẹni to ba mọ Jide Kosoko yoo jẹri si pe eniyan daadaa ni wọn, nitori naa mo tọrọ aforiji fun ọrọ ti wọn sọ pẹlu ibinu, to si ṣetan lati fa Iyabo Ojo ati Nkechi Blessing mọra.

Bakan naa ni Iyabo Ojo tọrọ aforiji ni ọwọ ẹgbẹ TAMPAN, awọn agbaagba ẹgbẹ to fi mọ Jide Kosoko.