You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Sunday Igboho: Elebuibon ní kìí ṣe pé ewé sunko fún Sunday Igboho, ìjàmbá làwọn DSS ṣe fún un
Oloye Sunday Adeyemo ti ọpọ mọ si Sunday Igboho jẹ ẹnikan ti ọpọ n wo gẹgẹ bi alagbara to kaato lati gbawọn eeyan silẹ lọwọ awọn afiya jẹni.
Idi niyii ti wọn maa fi n pe ni Igboho Oosa, ajijagbara ati ajafẹtọ ọmọniyan.
Eyi gan an lo jẹ ko wa lara awọn to n ṣe agbatẹru iwọde lati pe fun iyapa ati idasilẹ orilẹede Yoruba lara Naijiria.
- 'Ṣọ́ọ̀bù ìyá rẹ̀ ní Jumoke wá tí ìbọn ọlọ́pàá ti pa á lásìkò ìwọ́de Yoruba Nation ní Ojota'
- "DSS, níbo ni ₦2m àti owó Euro, Dollar àti Pound Sterling tẹ kó nílé mi wà? "
- Sunday Igboho, ìsáǹsá rẹ̀ kò lé sá mọ́ wa lọ́wọ́, mímú lá mú ọ - DSS fọwọ́ gbáyà
- Sunday Igboho ń ṣọ̀fọ̀ ọ̀kan lára àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tí DSS pa
- À ṣe ìwọ́de Yoruba Nation l‘Eko, bí ọlọ́pàá fẹ́, bó kọ̀ - Igun Sunday Igboho
- "Sunday Igboho, Banji Akitoye, ẹ rìn jìnnà sójú pópó Eko fún ìwọ́de Yoruba Nation"
- Wo ohun tó yẹ kí o ṣe sí ojú abẹ́ rẹ, ''vagina'' lẹ́yìn ìbálòpọ̀
Ṣugbọn kayeefi lo jẹ fun ọpọ ọmọ Naijiria papaa julọ nilẹ Yoruba, bi ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS ṣe raye wọ ile alagbara ajijagbara naa to wa lagbegbe Soka niluu Ibadan loru mọju Ọjọbọ.
Bẹẹ ni ọpọ n beere pe nibo ni Igboho wa, ti ko fi lee koju awọn osisẹ DSS to wa ko awọn ọmọlẹyin rẹ lai bikita fun oogun to ni.
Bakan naa ni wọn ni niwọn igba to jẹ pe alagbara ni Igboho, ko se fi awọn oogun naa raga bo awọn ọmọ lẹyin rẹ, tabi ko ti lo diẹ fun wọn, ti ibọn ko fi ni le ran wọn.
Nipari, awọn ọmọ Yoruba kan wa n beere pe se ewe sunko fun Sunday Igboho ni lasiko tawọn osisẹ DSS fi wa, ni ko se duro koju wọn, ko si se wọn bii ọsẹ ti n soju.
Ọna lati wa idahun sawọn ibeere yii lo mu ka tọ agba alagbara kan nilẹ Yoruba lọ, ẹni to tun jẹ gbajumọ Babalawo ti ko se fi ọwọ rọ sẹyin.
Elebuibon salaye ohun to sẹlẹ ti DSS fi ko bantẹ oogun Igboho lai farapa
BBC Yoruba kan si Araba Ilu Osogbo, Ifayemi Elebuibon lati ṣalaye ohun to ṣẹlẹ tawọn ajọ DSS fi rọna wọ ile Igboho, ti wọn si ko bantẹ oogun rẹ atawọn nkan iṣe agbara mii lọ lai si nnkan kan to se wọn.
Elebuibon fesi pe kii ṣe pe ewe sunko fun Igboho, amọ Ijamba lawọn ajọ DSS lọ ṣe fun Igboho nile rẹ nitori ko pe wọn n bọ tẹlẹ.
''To ba jẹ pe Igboho atawọn ọmọlẹyin rẹ ti mura silẹ de wọn ni, ohun ti a n wi yii kọ ni a baa maa wi.
Ṣugbọn ẹni to ṣadeedee ja wọ ile eeyan lai ro ti tẹlẹ, to si bẹrẹ si ni ji nkan eeyan ko.
O da bi igba ti eeyan lọ ba eeyan ni buba ni, ohun to tumọ si ni ilaluri ati ijamba, ati pe bi igba ti eeyan lọ ja eeyan lole ni,'' Elebuibon ṣalaye.
Elebuibon ko ṣai sọ pe ko si igba ti ewe ko le sunko fawọn alagbara papaa julọ ti wọn ko ba kiye sara.
O ni ẹbọ ju oogun lọ tori ẹbọ ni o maa n jẹ ki oogun jẹ ṣugbọn Araba ilu Osogbo ni ojiji lawọn DSS lọ ba Igboho nile.
Mọja-mọsa la n mọ akikanju loju ogun
Lori ọrọ ti ajọ DSS sọ pe Igboho salọ nigba tawọn atawọn ọmọlẹyin rẹ doju ibọn kọ awọn oṣiṣẹ DSS, Elebuibon ni mọja mọsa ni Igboho ṣe kii ṣe pe o fẹ fi awọn ọmọlẹyin rẹ silẹ fun iya jẹ.
Elebuibọn ni ''ologun ti ko ba mọja mọsa, iru wọn lo maa n ba ogun lọ.
Ohun ti a n wi yii kọ ni a ko ba maa wi ti Igboho naa ba koju awọn ajọ DSS to wa ka a mọle ni.''
Elebuibon ko ṣai bu ẹnu atẹ lu bi awọn ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS ti yabo ile Igboho lairo tẹlẹ.
''Ni ilu ọlaju, ohun to yẹ kawọn DSS ṣe ni pe, ṣe lo yẹ ki wọn pe Igboho lori aago wi pe ko wa fun ifọrọwanilẹnu, ko lẹtọọ ki wọn kan ṣadeedee dabọn bolẹ nile rẹ bi wọn ṣe ṣe.
Bi wọn ṣe maa n ṣe lorilẹede Amerika atawọn orilẹede ọlaju miran niyẹn.
Wọn rọgba yi ẹni naa ka ni titi ti oni tọun yoo fi fi ara rẹ le wọn lọwọ, awa o le kọ wọn niṣẹ wọn ṣugbọn awọn ohun ti awa ti ri lawọn ilu okeere ti awa n gbe niyẹn,'' Elebuibon lo sọ bẹẹ.
Elebuibon ni owe lọrọ bi awọn DSS ṣe yabo ile Igboho n pa fun iran Yoruba pe ki araba tun ra mu, tori odo ti n gbe arere lọ.