You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Iyabo Ojo: Èmi kí yóò kú ikú kíkú kán nítorí ọ̀rọ̀ Baba Ijesha, Yomi Fabiyi
Oṣerebinrin Iyabo Ojo ti kesi awọn to n ro ibi ro oun wi pe gbogbo wọn ni wọn yoo ba Ọlọrun oun nibẹ.
Iyabo Ọjọ sọ bẹẹ ninu atẹjade to kọ si oju opo ikansiraẹni Instagram, lẹyin ti o fi fidio lede nibi ti baba kan to gbe aṣọ iṣẹmbaye sọrun.
Ninu fidio ọhun ni baba agbalagba naa to dabi babalawo ti n sọrọ kubakugbe si Iyabo Ojo, to si ro iku si.
- CAN faraya lórí ikọlù agbofinro sàwọn ajàfẹ́tọ̀ bí Sunday Igboho
- Gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo, Ogun ti dé sí ibi ìsìnkú Wolìí TB Joshua tí yóò wọ káà ilẹ̀ sùn, bí ètò ṣe ńlọ rèé...
- Ó tó gẹ́, Sunday Igboho fẹ́ gbé ìjọba lọ ilé ẹjọ́ bí wọn kò bá tú àwọn èèyàn rẹ̀ sílẹ̀
- 'Ariwò tí ẹ̀ ń pa kò lè dóòlà ẹ̀mí Sunday Igboho, kò leè sá mọ́ ìjọba lọ́wọ́'
Amọ Iyabo Ojo ninu atẹjade ni oju opo rẹ sọ wi pe ibẹru kankan ko si fun ọmọ Ọlọrun, a ti pe ẹni to ba ro iku ro oun, ni yoo fi ori ara rẹ gbe.
''Baba Ijesha, Yomi Fabiyi ati gbogbo ẹni buruku ati awọn obinrin to n ṣe atilẹyin fun awọn ẹni ibi, ko fẹ ki ẹ mọ wi pe igbiyanju yin lori aye mi yoo jasi asan, ẹ kan n daamu ara yin lasan ni o.''
''Ẹ kiyesi o, Ọlọrun nkan lo ni agbara lati gba ẹmi ẹnikẹni ni igba ati asiko to ba yẹ''
''Ọlọrun nikan ni yoo gba gbogbo ogo lori aye mi, titi di igba naa, asan lori asan ni igbiyanju yin.''
- Gbogbo ìgbèsẹ̀ tí Sunday Igboho ń gbé ni mo mọ̀ sí gẹ́gẹ́ bí Aare Ona Kakanfo - Gani Adams
- Olórí Eléégún, Ìmáàmù àti èèyàn márùn-ún míì dèrò àtìmọ́lé l‘Osogbo
- "Gbàjarè! Àwọn èèyàn tí DSS kó nílé Sunday Igboho nílò ìtọ́jú kíámọ́sá"
- Iléeṣẹ́ DSTV àti GO TV rugi òyin lọ́dọ̀ ìjọba àpapọ̀
- Wo bí ètò ìsìnkú TB Joshua ṣe n wáyé ní ìlú abínibí rẹ̀
''Bi o le bẹru eniyan laye, ti ko si si ẹni to le dami duro lati s otitọ ni igba gbogbo.''
''Bakan naa ẹ ma gbagbẹ, ẹni to ba ni Ọlọrun, o ni ohun gbogbo.''
''Mi o bẹru iku nitori gbogbo wa ni yoo lọ, amọ asiko Ọlọrun nikan lo ṣe koko.''