Bode George sọ̀rọ̀ sókè lórí àwọn tó faragbọta lásìkò ìwọ́de EndSARS ní Lekki
Ọkan lara awọn eekan ati agba ninu ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, Oloye Bode George naa ti mẹnu ba ọrọ iṣẹlẹ to waye ni Lekki lasiko iwọde EndSARS ni ipinlẹ Eko.
Bode George ṣepade oniroyin ni ile rẹ to wa ni Ikoyi ipinlẹ eko nibi to ti sọ fun BBC Yoruba pe Asiwaju Bola Tinubu to jẹ agba ninu ẹgbẹ oṣelu APC kan n dibọn lasan ni ati pe ọrọ to sọ pe oun o gba nkankan nidii ibode Lekki ko ri bẹẹ.
- Bí ó bá wọlé lọ́dún 2023, ní tèmi, èṣù ló wọlé - Bode George
- Buhari, máṣe gbá ìpànìyàn Lekki sórí ààtàn, kò yẹ́ kí ológun yin ọ̀dọ́ níbọn - Bode George
- Ó ti pẹ́ tí Fayose ti máa ń sọ̀sọkúsọ, ṣé ó mutí yó ni àbí ó mugbó? - Bode George
- Ǹjẹ́ ẹ mọ pé kìí ṣe ènìyàn nìkàn ló ń ṣe òfin ìyàsọ́tọ̀ "social distance" lásìkò àìsàn?
- Àwọn tó mọ̀ nípa ìpànìyàn Lekki yóò fojú winá òfin - Sanwo-Olu sí Becky Anderson
Bode George jẹ ko di mimọ pe bi Tinubu ṣe n ri gba nibẹ lo ṣe jẹ pe ọmọ rẹ nikan ṣoṣo naa lo n ṣe akoso gbogbo nkan bii ina to wa nibi agbegbe ti wọn ni ki wọn pa ina ibẹ.
"Ajẹ ke lana, ọmọ ku loni, tani o mọ pe ajẹ to ke lana lo pa ọmọ jẹ.
Bode George gbe lẹyin awọn oluwọde pe ṣe ni wọn kan n bere fun ohun ti wọn fẹ lalafia. Amọ awọn ọ̀rọ̀ to sọ si Aṣiwaju Tinubu lo n lọ niwaju ninu fidio yii.