Election Tribunal: Atiku kùnà! Buhari ló borí ní ìgbẹ́jọ́ ìdìbò 2019

Oríṣun àwòrán, Others
Wọn ti kede Buhari pe oun lo jawe olubori lori ẹjọ ti Atiku pe lori idibo aarẹ to kọja
Ile ẹjọ to n gbọ ẹsun eto idibo lorilẹ-ede Naijiria, Tribunal ti wogile ẹjo ti oludije si ipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu APC pe.
Atiku Abubakar pe ẹjọ yii lati tako ibo to gbe Aarẹ Muhammadu Buhari wọle gẹgẹ bii Aarẹ ninu idibo gbogboogbo ti ọdun 2019.
Atiku fi ẹsun kan ẹgbẹ oselu APC wi pe wọn ṣe ọpọlọpọ magomago ninu idibo sipo aarẹ naa, ati pe ajọ eleto idibo INEC ko ṣe amọ ile-ẹjọ fagile awọn ẹsun naa.
PDP bere fun iwọgile awọn esi idibo aarẹ lati ipinlẹ Zamfara, Nasarawa, Bornu ati Yobe.
Ẹgbẹ oṣelu PDP tun ṣalaye pe ni ipinlẹ Yobe iye awọn eeyan to dibo pọ ju iye awọn oludibo ti wọn forukọ silẹ ni ipinlẹ naa, pẹlu ẹri wi pe iru ibo bẹ ko lẹṣẹ nlẹ.








