Bournemouth vs Tottenham: Báwo ni Tottenham se gba káàdì pupa méjì láàárín ìṣẹ́jú márùn ún?

BouvsTot

Oríṣun àwòrán, @afcbournemouth

Àkọlé àwòrán, Son lo kọkọ gba kaadi alawọ pupa nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ iṣẹju kẹtalelogoji ti Foyth si gba tirẹ ni iṣẹju kejidinlaadọta

Bi idije premiership ṣe n lọ si ibi ipari bayii ti awọn ẹgbẹ agbabọọlu si n lepa bi saa to n bọ yoo ṣe ri, ẹgbẹ agbabọọẹu Tottenham da ara rẹ lagbo da sina nigba to lọ ba Bournemouth ni ile ni ọsan ọjọ abamẹta.

Tottenham sọ ifẹsẹwọnsẹ naa di tawọn ọmọ girama pẹlu bi awọn agbabọọlu rẹ meji ṣe gba kaadi alawọ pupa eyi to tumọ si pe wọn le wọn jade kuro ninu ifẹsẹwọnsẹ naa fun iwa aṣemaṣe.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

nigba ti oludari ere yoo fi fun fere fun ifẹ̀sẹ̀wọ̀nsẹ̀ naa lati pari, Bournemouth lo bori pẹlu ami ayo kan si odo.

Aké ọmọ agbabọọlu Bournemouth lo gba goolu naa wọle nigba ti ifẹswọnsẹ naa wọ aadọrun iṣẹju

Son lo kọkọ gba kaadi alawọ pupa nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ iṣẹju kẹtalelogoji ti Foyth si gba tirẹ ni iṣẹju kejidinlaadọta.

BouvsTot

Oríṣun àwòrán, @afcbournemouth

Ẹgbẹ agbabọọlu Tottenham wa lara awọn ikọ to n lepa ipo mẹrin akọkọ lori akasọ igbelewọn liigi Premiership ti saa 2018/2019 eyi ti o jẹ pe ikọ meji, Manchester city ati Liverpool nikan lo ṣi daju fun.

Son lo kọkọ gba kaadi alawọ pupa nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ iṣẹju kẹtalelogoji ti Foyth si gba tirẹ ni iṣẹju kejidinlaadọta.