Police Force: Ọwọ́ Ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Zamfara tẹ adigunjalè 104

ajímàlùú adigunjalè

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, ajímàlùú adigunjalè

Àwọn Ọlọ́pàá amuṣẹ́yá ti pa àwọn adigunjalè mẹ́rìnlélọ́gọ́rùn ún, bẹẹ ni wọ́n ba kọlọfin ibi ti àádọ́ta awọn adigunle n sapamọ si jẹ.

Awọn ọlọpaa amuṣeya ọhun tun gba maalu ẹẹdẹgbẹta ati agutan mọkandinlọgọrin pada laagọ awọn ọdaran naa.

Atẹjade kan ti agbẹnusọ fun ile iṣẹ ọlọpaa fi sita fidii rẹ mulẹ pe ọlọpaa kan padanu ẹmi rẹ ninu ikọlu naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ni ọjọ kẹsan oṣu kọkanla ni ọga ọlọpaa lorilẹede Naijiria Ibrahim Idris paṣẹ pe ki ẹgbẹrun ọlọpaa amuṣẹya lọ si Ipinlẹ Zamfara lati mu awọn adigunle ti wọn n yọ awọn ara ipinlẹ naa lẹnu.

Ibọn

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ọwọ awọn ọlọpaa ba awọn adigunjalẹ

Ni bayii ọwọ ọlọpaa ti ba awọn afurasi marundinlaadọrun un, bẹe ni wọn si ti gba ibọn AK 47 mẹtadinlọgbọn pẹlu ibọn atọwọrọ mejilelaadọta ati ọpọlọpọ nnkan ija oloro.

Awọn ọlọpaa amuṣẹya ti da ọta le lugba o le mẹsan maalu ati agutan ọgọrun o le mẹsan ti wọn ri gba pada fun awọn to ni wọn ọn.

Ẹwẹ, ile iṣe ọlọpaa ti rọ awọn ara Ipinlẹ Zamfara lati pe awọn nọmba wọnyii ti wọn ba kẹfin ọdaran kankan nibi kibi: 08037025670, 08033210966, 08033312261, 08123829666, 09053872244, 07082351758, 08091914752.