Ìjọba Naijiria: À ń se ìwádìí lórí àwọn oníwàásù Sokoto tó ń gbé ìbọ̀n

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Agbẹnusọ fun Aarẹ Muhammadu Buhari, Garba Shehu ti sọ wi pe ijọba apapọ yoo bẹrẹ iwadii lori awọn oniwaasu ti wọn lo n gbe oun ija kaakiri lagbeegbe kan ni Sokoto.
Iroyin kan ti o n da ẹru ba ọpọ lẹkun ariwa orilẹede Naijiria, paapaa julọ ni ipinlẹ Sokoto ni ti ẹgbẹ agbebọn tuntun kan ti wọn ni wọn n waasu ẹsin Islam tawọn tibọn lọwọ.
Iroyin sọpe orilẹede Niger ni awọn ẹgbẹ alakatakiti yii ti ṣẹ wọ ẹkun iwọ oorun ariwa orilẹede Naijiria.
garba shehu fikun wipe ijoba naijiria ko ni fi isele yii jafara, amo won yoo kesi awon elebo aabo lati wo bi o se n lo lawon agbeegbe yii.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ẹgbẹ́ alákatakítí agbébọ̀n tuntun wọ Nàìjíríà!
Olugbe ijọba ibilẹ Tangaza kan nipinlẹ Sokoto ti o ba BBC Hausa sọrọ ṣalaye pe nnkan bi oṣu meji sẹyin ni awọn ẹgbẹ naa wọn awọn ileto kan ni ijọba ibilẹ naa.
Arakunrin naa ti o bẹbẹ pe ki BBC o fi orukọ bo oun laṣiri fi kun un pe awọn ẹgbẹ agbebọn naa tilẹ n rin lati ileto si ileto lati gba owo ori ti wọn si n yọ ẹgba si awọn eeyan ti wọn ba wo pe wọn ṣẹ tako ofin ẹsin Islam.
Bakan naa ni o ṣalaye pe awọn ọmọ ẹgbẹ alakatakiti naa ti wọn to igba ni iye kii ṣe alawọ dudu, wọn fara jọ awọn larubawa ti wọn fi lawani bo ori pẹlu awọn ibọn atamatase ni ọwọ wọn.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
O ni awọn ọmọ ẹgbẹ yii a tun maa gbe awọn ọmọde wọ inu igbo lọ lati kọ wọn ni oriṣiriṣi ẹkọ nigba ti wọn pada de. Wọn si tun fun wọn ni alupupu ọfẹ.
Ijọba ibilẹ Tangaza ni ipinlẹ Sokoto sun mọ orilẹede Niger, nibẹ ni wọn ṣi wa bayii.
Orilẹede Naijiria ṣi n ba wahala ati ipenija ikọ agbebọn Boko Haram finra bayii eleyii to ti mu ọpọlọpọ ẹmi lọ ti pupọ si ti di alainilelori.













