Ọlọ́pàá mú òṣìṣẹ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n fún ìdigunjalè

Oríṣun àwòrán, Enugu Police Command
Oṣiṣẹ ileeṣẹ ijọba tọ n ṣakoso ọgba ẹwọn kan, Collins Ugwu ni awọn ọlọpàá Ipinlẹ Enugu ti mu bayii lori ẹsun pe o wa ninu ẹgbẹ adigunjale kan.
Ugwu to nṣiṣẹ ni olu ileeṣẹ́ ọgba ẹwọn to wà ni Abuja jẹ ọmọ Ipinlẹ Ebonyi. Wọn mu u pẹ̀lu awọn afunrasi meji ti ọlọpàá ni wọn jìjọ maa n ṣọ awọn to ba lọ gb'owo ni ile ifowopamọ lati ja wọn lole.
Kọmiṣọna ọlọpaa Ipinle Enugu Mohammed Danmallam ti o foju awọn afunrasi naa han awọn akọroyin ni wọn ri Ugwu ati awọn akẹgbẹ rẹ mu lẹyin ti wọn ri awọn aridaju kan lori bi wọn ṣe n ṣọṣẹ́.
Danmallam ṣalaye pe agbegbe awọǹ ile ifowopamọ ni awọn afunrasi naa maa n gbe ki wọn baa le ṣọ awọn ti wọn ba fẹ ja lole.
O ni, "Wọn tun maa n ra ọja lọwọ awọn oniṣowo laisan owo, ṣugbọn oniṣowo naa yoo ri atẹjiṣẹ lati banki bi ẹni pe owo naa ti wọle. Ọjọ kẹrindinlọgbọn osu kẹfa ni a ri wọn mu ni popona Ogui ni Enugu."
Kọmiṣọna ni awọn yoo gbe awọn afunrasi naa lọ ile ẹjọ ti iwadii ba ti pari.








