Ajọ Apinnaka TCN :Ibudo àmúsagbára Mẹ́fà ló bàjẹ̀

òpó iná

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Mbah fi kún pé yàtọ̀ sí iroyin ti wọn ń tàn kálẹ́ pé àwọn òpó iná tó ń gbéna kiri ló bajẹ àwọn ibùdó àmúsagbara ni ọ̀rọ̀ náà kan

Ilé iṣẹ́ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ iná pínpín lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà (TCN) tí sọ pé iná mọ̀nàmọ́ná tí ń ṣe mọ́namọ̀na láwọn apá ibì kan lórílẹ̀-èdè Nàìjìríà wáyé nítorí àwọn irinṣẹ́ tó dẹnukọlẹ̀.

Nínú àtẹ̀jáde tí agbẹnusọ ilé-iṣẹ́ ọ̀hún Ndidi Mbah, fi síta pé àwọn ohun àmúṣagbára mẹ́fà ló ti dẹnukọlẹ̀ káàkiri.

Ó ní àwọn ilé-ìṣẹ́ Gáàsì Nàìjíríà ( NGC) tí fi léde ní ọjọ́ kẹẹ̀dógún osù yìí pé gbogbo rẹ̀ ti jẹ́ra tan, atipe àwọn kanga àfẹ́fẹ́ tí Shell náà ti ní ìsòro ní ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù yìí bákan náà.

Èyí ní wọn ló ṣokùnfà ẹgbẹ̀rún kan lé méjìlélọ́gọ́rin mẹgawaati tó já kúro nínú iná àmúṣagbára Nàìjíría.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò, Abiola: Mínístà Adewole jẹ nínú ànfààní ọ̀la rẹ̀

Àtẹ̀jáde ọ̀hún ní àwọn ibùdó àgbara tí ọ̀rọ̀ ọ̀hún kan ní Ihovbor, Azura, Omotosho gas, Geregu gas, Olorunsogo gas, Sapele àti ibùdó àmúsagbára Egbin to ń gbiayànjú àti sàkójọ ọgọ́ta mẹgawaati, ibùdó àmúsagbara Afam VI.

Mbah fi kún un pé yàtọ̀ sí iroyin ti wọn ń tàn kálẹ́ pé àwọn òpó iná tó ń gbéna kiri ló bajẹ àwọn ibùdó àmúsagbara ni ọ̀rọ̀ náà kan.

Ó ní àwọn NGC ń ṣiṣẹ̀ takuntakun láti ríi dájú wípe ọ̀rọ̀ níyanjú.