You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
NAPTIP: Ẹ ṣọ́ra fáwọn tó ń fi ẹ̀tàn kó ọ̀dọ̀ lọ sí Russia
Ajọ to n gbogun ti kiko awọn eeyan ṣowoo kotọ lorilẹede Naijiria, NAPTIP ni awọn ṣi n reti awọn ajọ ti ijọba apapọ paṣẹ fun lati mu orukọ awọn ti wọn n ran lọ s'orilẹede Russia fun idije FIFA 2018 wa fun ayẹwo.
Ajọ NAPTIP ni gbogbo awọn ajọ, ileeṣẹ ati ijọba lẹkajẹka gbogbo ti wọn n ran awọn eeyan lọ si orilẹede Russia ni ijọba apapọ ti ni ki wọn gba aṣẹ 'o wẹ yan kainkain' lọwọ ajọ naa ki wọn to mu irinajo wọn pọn lọ si Russia.
Oludari ẹka iwadi ati itọpinpin ni ajọ NAPTIP, Josiah Emerole lo yannana ọrọ yii nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ lori awọn afunrasi kan ti ọwọ ba ni papakọ ofurufu Muritala Mohammed to wa nilu Eko ti wọn n gbimọran ati ko awọn ọdọ mẹwa lọ si orilẹede Russia fun owo kotọ.
Ni ọjọ abamẹta to kọja lọwọ awọn oṣiṣẹ ọtẹlẹmuyẹ ajọ naa tẹ awọn eeyan marun kan, Esan mathew to jẹ ọlọpa, Stephen Fayẹmiwo to jẹ oṣiṣẹ ayẹwo, Azeez Olowo, Idowu fashakin ati Eni Godwin.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ajọ NAPTIP ni ajọ ere bọọlu lorilẹede Naijiria, NFF nikan lo tii fi orukọ awọn eeyan to n ran lọ si Russia fun idije ife ẹyẹ FIFA ṣọwọ fun ayẹwo ni ajọ NAPTIP.
"Oludari agba ajọ NAPTIP ti sin araalu ni gbẹrẹ ipakọ ṣaaju asiko yii pe awọn kọlọransi ẹda kan yoo maa fi idije ife ẹyẹ FIFA ti yoo bẹrẹ ni Russia boju lati ko awọn eeyan lọ si oke okun fun owoo kotọ. Ara wọn ni a si ti n ri bayii"
Oludari ẹka iwadi ati itọpinpin ni ajọ NAPTIP wa fi da awọn araalu loju pe awo oju lalakan fii ṣọri ni ajọ naa ti da bayii lati rii pe awọn ti ko ni iṣẹ to tọna lati ṣe lorilẹede Russia ko raaye ati lọ kuro lorilẹede yii lọna ti ko tọ.