You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Mohammed Salah: Ko ko ko lara mi le
Gbajugbaja agbabọọlu ọmọ orílèèdè Egypt Mohammed Salah ní ará òun tí yà láti kópa nínú ifẹsẹwọnsẹ àkọkọ Egypt pẹlú Uruguay ni ìdíje ife àgbáyé ní Russia.
O fi ọ̀rọ̀ yìí lédè fún Ààrẹ Egypt Abdulfattah Elsisi nígbà tí o gba ìkọ agbaboolu Egypt lalejo lọ́jọ́ àbámẹ́ta ni ilé ìjọba.
Bákannáà sí ní áwọn ọmọ orílèèdè rẹ fi tijo tayo kí i káàbò sórí pápá iṣere níbi igbaradi ìkẹyìn ìkọ Egypt .
Lójú òpó Twitter fídíò ìkíni náà ti gbálè.
Ṣugbọn Salah kò bawon kópa nínú igbaradi náà.
Orílẹ̀èdè Egypt ti kún fún àdúà lẹyìn ìgbà tí Salah f'arapa nínú ifẹsẹwọnsẹ asekagba idije Champions league pẹlu fún ẹgbẹ agbaboolu Liverpool.
O ti n gba ìtọjú lórí ejika rẹ tó fi ṣẹṣẹ láti ìgbà náà.
Salah wa lára àwọn ìràwọ̀ ìkọ agbabọọlu Egypt ti o sí kó ipá ríbiríbi lati rí wí pé Egypt tẹsíwájú láti kópa nínú ìdíje àgbáyé ẹlẹẹketa irú rẹ.
Egypt, Naijiria, Senegal, Morocco ati Tunisia wa lara áwọn orílèèdè Afrika tí yóò kópa nínú ìdíje àgbáyé Russsia 2018.