You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ramos: Èmi kọ́ ni mo ṣe Salah léṣe
Adilemu ikọ Real Madrid, Sergio Ramos ti sọ pe, oun kọ lo ṣe ẹlẹsẹ ayo ikọ Liverpool, Mohamed Salah leṣe, ninu idije aṣekagba Champions League.
Ramos ṣalaye pe, Salah lo kọkọ f'ọwọ kọ oun lapa nigba ti oun fẹ gba bọọlu lẹsẹ rẹ, ninu ifẹsẹwọnsẹ naa.
Salah kuro lori papa iṣere pẹlu omi ẹkun loju, lẹyin igba to farapa pẹlu ejika rẹ, o si ti ṣe iṣẹ abẹ lori ifarapa naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Sugbọn Ramos sọ pe o yẹ ki Salah le tẹsiwaju ninu idije naa, to jẹ pe wọn fun labẹrẹ lesẹkẹsẹ.
Salah yoo ṣoju orilẹede Egypt, ni ife ẹyẹ agbaye Russia 2018, bo tilẹ je pe ko ti gbadun apa rẹ daradara nítorí ifarapa naa.
Ẹwẹ, agbẹjọro kan to jẹ ọmọ orilẹede Egypt, ti pe Ramos lẹjọ, tó sì ń bèèrè owó to to £874m, lórí ipalara ti ifarapa Salah ṣe fun awọn ọmọ orilẹede naa.