Liverpool padà láti ibi tí wọ́n ti lọ ṣe ìgbáradì nínú òòrùn

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ikọ Liverpool ti pada si ilẹ Gẹẹsi l'ọjọ Aiku lati tẹsiwaju pẹlu igbaradi wọn fun ifẹsẹwọnsẹ aṣekagba idije Champions League pẹlu ikọ Real Madrid.
Ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool naa lo ti wa ni apa gusu orilẹede Spain lati gba oorun sara bi wọn n ti gbaradi fun ifẹsẹwọnsẹ ọhun ti yoo waye l'ọjọ Abamẹta nilu Kiev.
Nibayi ikọ Liverpool yoo bẹrẹ abala to kẹyin ninu igbaradi wọn ki wọn to maa lọ si ilu Kiev l'orilẹede Ukraine ninu oṣẹ yii.
Ẹwẹ, akọnimọgba ẹgbẹ agbabọọlu naa Jurgen Klopp sọ pe oun ko ni sọ fun awọn agbabọọlu rẹ lati lo ọna to yatọ nigbati wọn ba koju Real Madrid.
Ikọ Real Madrid ni ami ẹyẹ naa wa lọwọ wọn lẹyin igbati wọn gba lera wọn lẹmeeji.
Ni ọdun 2005 ni ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool ti gba ami ẹyẹ Champions League kẹyin.








