Iléẹ́jọ́ fún EFCC l’ásẹ láti gbégi lé owó Ayodele Fayose

Aworan Ayo Fayose

Oríṣun àwòrán, Facebook/Lere Olayinka

Àkọlé àwòrán, Ayo Fayose je alatako to foju han si ijọba orilẹẹde Naijiria

Ileẹjọ kotẹmilọrun kan to fikalẹ si ilu Ado Ekiti ni ipinlẹ Ekiti ti paṣẹ pe ki wọn gbẹsẹle asuwọn ifowopamọsi Gomina ipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Ayọdele Fayoṣe.

Ninu idajọ to gbe kalẹ ni ọjọọbọ ni ileẹjọ naa ti faaye gba ajọ to n gbogunti ṣiṣe owo ilu baṣubaṣu, EFCC lati fi agadagodo le aṣuwọn naa.

Ileẹjọ giga apapọ kan nilu Ado Ekiti lo ti kọkọ gbe ẹsẹ ajọ EFCC kuro lori aṣuwọn Gomina Fayoṣe pẹlu awijare pe gẹgẹ bii anfani, koṣeebawii ti ofin ilẹ Naijiria fifun un gẹgẹ bii gomina, aṣiṣe nla ni fun ajọ EFCC lati pàalè aṣuwọn ifowopamọsi rẹ.

Amin iyasọtọ kan

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Amin iyasọtọ kan

Ti a ko ba gbagbe, ni ọdun 2016, adajọ agba ti ileẹjo giga to kalẹ si Ekiti pasẹ ki ajo EFCC o gbẹsẹ kuro lori apo asuwọn rẹ mejeeji, lẹyin ti ajọ naa fẹsun kan gomina naa lori owo ribiti to wa ninu apo isuna rẹ.