Malaria Vaccine: Àjọ WHO gbé abẹ́rẹ́ àjẹsára àìsàn ibà jáde fún ilẹ̀ Afrika

Ajọ eleto ilẹra lagbaye, WHO ti sapejuwe abẹrẹ ajẹsara tuntun ti wọn gbe jade fun aisan iba pe ohun ṣiṣẹ tako arun naa ni agọ ara.

Ajọ WHO gbe abẹrẹ ajẹsara naa jade lẹyin ti ileeṣẹ apoogun GSK lo fun awọn eniyan ni awọn orilẹede mẹta.

Lasiko ti wọn n ṣe aṣẹwo abẹrẹ ajẹsara naa ni Malawi, Ghana ati Kenya ni wọn ri pe lọna ida ogoji ti abẹrẹ ajẹsara naa fi koju arun iba.

O kere tan ẹgbẹrun lọna irinwo eniyan ni aisan iba n pa ni ọdọọdun, ti ida awọn to n lugbadi aisan naa si jẹ ọmọde ti ko i tii pe ọdun marun un ni ilẹ Afrika.

Adari Ajọ WHO, Tedros Ghebreyesus sapejuwe abẹrẹ ajẹsara naa gẹgẹ bi aṣeyọri nla fun awọn eniyan ni ilẹ Afrika ati ni agbaye pẹlu.

O ti lẹ ni ẹgbẹrun ọdun ti wọn ti n gbiyanju lati ṣe abẹrẹ ajẹsara ti yoo koju aisan iba lai si aṣeyọri kankan lori rẹ.

Nibayii ti wọn ti sẹ aṣeyori lori abẹrẹ ajẹsara naa, eleyii jẹ iṣẹ nla fun awọn oniṣegun oyinbo ati apoogun kaakiri agbaye.

Abẹrẹ ajẹsara naa ti wọn pe orukọ rẹ ni RTS,S - ti ṣiṣẹ lati gbogun ti aisan iba fun ọdun mẹfa ki wọn to fi ọwọ rẹ soya bii abẹrẹ ajẹsara to lamilaaka.

Ajo WHO ni eleyii yoo doola ẹmi ẹgbẹgbẹrun awọn ọmọde kaakiri agbaye ati ilẹ Afrika ti aisan iba ti n ba wọn finra julọ.

Aisan iba apaniyan

Aisan iba jẹ ọkan lara awọn aisan to n da sẹli ẹjẹ,blood cells ru lẹyin ti ẹfọn ba ti jẹ eniyan.

Awọn oogun to n gbogun ti aisan iba yii ati awọn oogun ẹfọn ti mu ki aisan iba dinku laarin awọn eniyan.

Ọpọlọpọ awọn eniyan ni ilẹ Afrika ni wọn n fi ara gba ninu ijamba aisan iba nitori o kere tan ọmọde to to 260,000 ni aisan iba naa mu ẹmi wọn lọ ni ọdun 2019.