Kwara family food poiison death: Ọmọ ìyá kan náà mẹ́ta kú lẹ́yìn tí wọ́n jẹ Àmàlà ní Ilorin

Ọfọ̀ nla miran tun ṣẹ nijọba ibilẹ Ilorin East, nipinlẹ Kwara lọjọ Ìṣẹ́gun, lẹyin ti eeyan mẹta kú ninu ẹbi kan.

Iroyin ti a ko ti i le fidi rẹ mulẹ sọ pe majele wa ninu oúnjẹ kan ti wọn jẹ lo fa iku ojiji.

A gbọ pe ọmọ iya kan naa marun-un ni iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ si lẹyin ti wọn jẹ amala tán.

Ni kete ti wọn jẹ oúnjẹ naa tan ni wọn bẹrẹ si ni pariwo inu rirun, ti wọn si tun n bi.

Eyi to mu ki wọn o gbe wọn lọ sileewosan kan nilu Ilorin.

Awọn mẹta ni aisan kọkọ bẹrẹ lara wọn, ti wọn si gbe wọn lọ si ileewosan itọju àwọn ọmọde Children's Specialists Hospital, Ilorin.

Nibi ti wọn ti n gbiyanju lati doola ẹmi awọn mẹtẹẹta, ni wọn tun gbe awọn meji yooku lọ si ileewosan miran.

Ni ileewosan si ni wọn ti sọ fun wọn pé àwọn mẹta akọkọ ninu wọn ti kú.

Agbenusọ fun ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Ajayi Okasanmi sọ pe oun ko gbọ nipa iṣẹlẹ naa, àmọ́ oṣiṣẹ kan ni ajọ to n mojuto ọrọ aarun, Alhaji Muhammad Abdullahi fidi iṣẹlẹ naa mulẹ.

O ni awọn meji tó kù naa si ti kuro nileewosan.

"Baba awọn ọmọ naa, to jẹ agbẹ sọ fun wa pe oun ni oun gbin ẹ̀gẹ́ ti wọn fi ṣe elubọ, ti oun ko si le sọ nkan to mu ko fa wahala naa.