Yoruba Nation agitation: Sunday Igboho, Akintoye àtàwọn míràn fa Buhari, Malami àtàwọn míì lọ síwájú ilé ẹjọ́ àgbáyé ICC

Adari ẹgbẹ Ilana Ọmọ Oodua Ọjọgbọn Banji Akintoye, aṣiwaju ipe fun idasilẹ orilẹede Yoruba ti pe Buhari lẹjọ.

Akintoye, Sunday Igboho atawọn ẹgbẹ ajijagbara ilẹ Yoruba mọkandinlaadọta ti fọwọsi iwe ẹhonu oloju ewe mẹtadinlọgbọn kan ti wọn gbe tọ ile ẹjọ agbaye, ICC lọ.

Gẹgẹ bi ohun ti iwe iroyin ojoojumọ ilẹ wa ni awọn ri gba gẹgẹ bi iroyin, Amofin Aderẹmi Ọmọjọla lo fi iwe ẹhonu naa ranṣẹ lorukọ wọn.

Ninu iwe ẹhonu naa, wọn fi ẹsun pipa awọn ọmọ Yoruba ni ipinlẹ Ekiti, Ọṣun, Ondo, Ogun, ati ilẹ Okun ni ipinlẹ Kogi ati Kwara kan awọn adari Naijiria kan.

Lara awọn ti wọn pe lẹjọ ni Aarẹ Muhammadu Buhari, minisita feto idajọ Abubakar Malami, olori ileeṣẹ ọmọ ogun oriilẹ tẹlẹ, Tukur Buratai atamọ ọga agba ọlọpaa tẹlẹ bii Ibrahim idris ati Muhammed Adamu.

Awon miran ni: Olori ileeṣẹ aṣọbode Hammid Alli, Ọga ọlọpaa Alkali Baba, olori ileeṣẹ ọmọogun ilẹ Farouk Yahaya, olori ileeṣẹ ọmọogun ofurufu tẹlẹ, Sadiq Abubakar,

Awon mii ni: olori ajọ sifu difẹnsi tẹlẹ Ahmed Audi, ọgaagba ileeṣẹ wọle wọde Naijiria, Mohammed Babandede pẹlu olori ajọ sifu difẹnsi bayii, Abdullahi gana Muhammadu.

Iwe ẹhonu naa fi ẹsun kan awọn eeyan naa pe wọn lọwọ si pipa awọn ọmọ ẹgbẹ ajijagbara to pẹjọ naa, wọn si ṣe wọn leṣe.

Nibayii ileẹjọ agbaye ICC ni awọn ti tẹwọ gba iwe ẹhonu naa.