Airtel office near me: Lóòtọ́ èmi ni mo ṣagbátẹrù òpó alátagbà Airtel lọ sí Ago Owu ṣùgbọ́n kìí ṣe àkànṣe iṣẹ́ agbègbè mi- Senator Adelere Oriolowo

Lori ọrọ iṣẹ akanṣe iṣẹ opo ibanisọrọ alatagba Aitel kan ni agbegbe Agọ Owu Farm settlement ti wọn ni Sẹnatọ to n ṣoju ẹkun iwọ oorun ipinlẹ Ọṣun ṣi gẹgẹ bi akanṣe iṣẹ la wa.

Iṣẹ akanṣe eyi jẹ iroyin to n ja ranyinranyin lori ayelujara bayii.

BBC ti kan si Sẹnetọ Adelere Oriolowo ti sọ pe lootọ ni ṣugbọn aigbọrọ jalẹ lo n da awọn to gbe iroyin naa kiri laamu.

Ninu ọrọ to ba BBC News Yoruba sọ, Sẹnetọ Oriolowo ni lootọ oun loun ṣokunfa bi opo alatagba ibaraẹnisọrọ ileeṣẹ Airtell naa ṣe de agbegbe ọhun.

Sugbọn oun ko sọ fun ẹnikẹni tabi kọọ sori iṣẹ naa pe akanṣe iṣẹ idagbasoke agbegbe (constituency project) oun ni.

"Ibi ti wọn gbe opo alatagba ibaraẹnisọrọ si yẹn, ṣe ilu naa ṣẹṣẹ de ibẹ ni bi mo ba kọ pe emi ni mo ṣe agbatẹru bi opo alatagba ibaraẹnisọrọ naa ṣe de ibẹ, ṣe ẹṣẹ n bẹ nibẹ?"

"Ki ni yii ti wa nibẹ tipẹ. Igba ti mo lọ ṣe ipolongo idibo lọdọ wọn ni wọn sọ pe awọn n fẹ ọna ibaraẹnisọrọ lọdọ awọn naa. Ni mo ṣe gbe igbesẹ ni kete ti mo wọle."

Sẹnetọ Oriolowo ni 'Mo ṣokunfa kini yii yatọ si pe emi ni mo ṣee sibẹ.

Bakan naa lo fidi rẹ mulẹ pe awọn eeyan agbegbe naa lo mu aba wa pe awọn naa fẹ fẹ ayẹyẹ ṣiṣi rẹ loju, kii ṣe oun ati pe oun gan ko si nibi ayẹyẹ ṣiṣi opo alatagba ibaraẹnisọrọ naa.

Èrò ọmọ Nàìjíríà ṣọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórí Sẹ́nétọ̀ Adelere Oriolowo, APC tó fi opó ẹ̀rọ ayélujára Airtel ṣe iṣẹ́ àkànṣe ìlú ní Osun

Ọkan lara awọn ṣẹnetọ lẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Osun, Adelere Oriolowo ti fi opo ayelujara ileeṣẹ Airtel han gẹgẹ bi iṣẹ akanṣe ẹkun rẹ to ṣe.

Oriolowo to n ṣoju ẹkun Iwọ Oorun ipinlẹ Osun ni Ile Igbimọ Aṣofin lo safihan iṣẹ akanse naa ni agbegbe Ago Owu Farm Settlement.

Ninu aworan opo ayelujara naa ti iroyin sọ pe sẹnetọ Odeyemi Oriolowolo ṣe agbatẹru rẹ lo ni akọle pe ''Ileri ti APC ṣe ti di mimu ṣẹ''.

Amọ, titi di asiko yii ileeṣẹ Airtel ko i ti fesi si isafihan iṣẹ akanṣe naa.

Iroyin ni ọdun to kọ̣ja ni Sẹnetọ naa ṣeleri lati lo gbogbo igbesi aye oun to ku lati sin ilu ati awọn ọmọ eniyan lapapọ, paapaa awọn to wa ni ẹkun ọhun.

Oriolowo sọ awọn ọrọ yii lasiko to n gba ami ẹyẹ ni agbegbe Akobo, ni ilu Ibadan, nipinlẹ Oyo.

O sọ nigba naa pe iwuri ni ami ẹyẹ naa jẹ fun oun, to si ṣe ileri wi pe oun yoo fi gbogbo aye oun sin awọn eniyan.

Ṣẹnẹtọ naa ni imọ lai si iwa ọmọluwabi, asan lo jasi, nitori naa ni wọn gbọdọ ma a sa ipa wọn ni igba gbogbo.