Governor Inuwa Yahaya: Ìjọba Gombe kọ́ iléẹ̀kọ́ sí ẹgbẹ́ àwọn iléeṣẹ́ elétò aàbò láti kojú àwọn ajínigbé

Gomina Yahaya ni ijọba oun n kọ awọn ileẹkọ nla nla naa si ẹgbẹ awọn ibudo awọn ẹṣọ alaabo lati dẹkun ijinigbe awọn akẹkọo ̣nipinlẹ naa.

Ijọba ipinlẹ Gombe ni awọn ti bẹrẹ si ni kọ awọn ileẹkọ to ga soke lati le gba ọpọlọpọ awọn akẹkọọ si lati dẹkun ijinigbe ojoojumọ.

Gomina ipinlẹ Gombe, Muhammad Inuwa Yahaya lo sọ bẹẹ ni Ọjọ Aje lasiko to n ṣepade pẹlu adari oṣiṣẹ aarẹ Buhari, Ibrahim Gambari ni ileeṣẹ Aarẹ ni ilu Abuja.

Gomina Yahaya ni ijọba oun n kọ awọn ileẹkọ nla nla naa si ẹgbẹ awọn ibudo awọn ẹṣọ alaabo lati dẹkun ijinigbe awọn akẹkọo ̣nipinlẹ naa.

Bakan naa lo ni ijọba oun gbe igbesẹ naa lẹyin ti wọn ṣewadii ijinigbe ni agbegbe naa, ati ọna abayọ lati da abo bo awọn akẹkọọ nipinlẹ naa.

''A ṣe ayẹwo awọn ileẹkọ wọnyii ati bi awọn ajinigbe ṣe ni anfaani lati wọ ibẹ ati awọn igbesẹ lati koju ipenija wọnyii ni awọn ileẹkọ.''

''Lẹyin naa ni a bẹrẹ si ni kọ awọn ileẹkọ nla nla fun awọn akẹkọọ lati le ko wọn jọ pọ sibẹ, paapaa awọn ti awọn ajinigbe ti ṣekọlu si ileẹkọ wọn tẹlẹ, ti ati pada si ileẹkọ si di iṣoro fun wọn.''

Gẹgẹ bi ọrọ gomina naa, agbegbe ti ipinlẹ Gombe wa laarin awọn ilu to wa ni ila-oorun ariwa orilẹede Naijiria, mu ki awọn ipenija aisi eto aabo to n ba wọn finra ni awọn agbegbe yii wọnu ilu Gombe.

Bakan naa ni Gomina ohun fikun pe awọn n ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn lọbalọba, to fi mọ awọn adari ẹsin ki ibaṣepọ to dan mọran le wa laarin awọn araalu.

Gomina ipinlẹ Gombe naa ni oun dupẹ pe alaafia jọba nipinlẹ naa ati wi pe awọn araalu gbọ ara wọn ye lai si rogbodiyan tabi wahala kankan.