Ọmọ Naijiria 350 ló dèrò ọ̀run nínú ìjàmbá ọkọ̀ ojú omi lọ́dún 2020

Ko din ni aadọta le lọọdunrun eeyan to ba omi lọ lẹyin ijamba ọkọ oju omi ni Naijiria lọdun 2020.

Alaga ileeṣẹ to n ri si idagbasoke awọn agbegbe ti wọn ti n pese ina ijọba, HYPPADEC, Joseph Ityav, lo fi ọrọ naa lede ni ipinlẹ Niger.

Ityav lo sọ ọrọ naa niluu Malale, ni ijọba ibilẹ Borgu lasiko ti wọn n ṣe ifilọlẹ gige awọn igi to wo sinu odo Kainji ati Shiroro.

O ni wọn n ṣe akanṣẹ iṣẹ naa pẹlu ajọṣepọ ileeṣẹ to n ri si ọrọ omi ni Naijiria.

Ityav sọ pe awọn ijamba naa n waye nitori ipo ti ọpọ ọkọ oju omi wa ni Naijiria, bi wọn ṣe maa n ko ero akoju to fi mọ awọn igi to wo sinu omi.

O ni ti wọn ba ti ko awọn igi to wa loju omi atawọn idọti naa tan, adinku yoo de ba iye ijamba to n waye ati iṣoro ti awọn olugbe agbegbe eti omi n doju kọ.

Lasiko to n sọrọ, adari agba ileeṣẹ HYPPADEC, Abubakar Yelwa ni ileeṣẹ ọhun yoo bojuto awọn iṣoro ati ifẹmiṣofo to waye lasiko ti wọn n ṣatunṣe adagun omi Kainji ati Shiroro.

Ọdun 1964 ni wọn kọ adagun omi Kainji pẹlu $209 miliọnu, ti wọn si ṣi lọdun 1968.

Nigba ti wọn kọ adagun omi Shiroro nipinlẹ Kaduna lọdun 1983.