You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Dare Adeboye's biography: Àwọn èèkànlú ń kẹ́dùn pẹ̀lú bàbá olóògbé
Ọjọ kẹfa, oṣu Karun un, ọdun 2021 ni iroyin iku alufa Dare Adeboye fa ori ayelujara ya.
Iroyin iku rẹ da omi tutu si ọkan gbogbo eeyan, paapaa awọn ọmọ ijọ Redeemed Christian Church, RCCG, ni Naijiria ati loke okun.
Dare Adeboye nigba aye rẹ jẹ ọkan lara awọn ọmọ alufa agba, to tun jẹ adari ijọ RCCG kaakiri agbaye, pasitọ Enoch Adejare Adeboye.
- Ohun tí ìyàwó Adeboye ṣe ní ìgbà akọkọ tó fojú hàn lẹ́yìn ikú ọmọ wọn Dare
- Háà, àṣé Pastor Adeboye kò léè dá èékánná ara rẹ̀ gé, àwọn ọmọ Nàìjíríà kan pariwo
- Ẹ wo bí ìyàwó Pasitọ Adeboye ṣe sàpèjúwe rẹ̀
- Adeboye sọ̀rọ̀ lórí ètò pápá ìjẹko RUGA
- Pásítọ̀ Adeboye bú ẹnu àtẹ́ lú ìjọba tó fofin dé ìsìn ìrékọjá sí ọdún tuntun
- Àwọn ìgbà tí ìmọ̀ràn Pásítọ̀ Adeboye lóri igbéyàwó ti fa àríyànjiyàn
- Èmi kìí se Ọlọ́run, ẹ yé lo fọ́tò mí fún ẹ̀bùn - Adeboye
- Ikú Dare Adeboye kò ní ǹkankan ṣe pẹ̀lú Covid-19, a bẹ̀bẹ̀ láti dá wà lákòókò yìí - Ẹbi Adeboye
Wo awọn ohun to yẹ ki o mọ nipa oloogbe naa:
Wọn bi Dare Adeboye ni ọjọ kẹsan an, oṣu Kẹfa, ọdun 1979.
Dare jẹ olukọ awọn ọdọ, o jẹ ẹnikan to ko awọn eeyan mọra, o si tun jẹ ọkan pataki lara awọn ọdọ to lẹnu lọrọ ati ilumọka ninu ijọ RCCG.
Orukọ ti ọpọ awọn ọdọ ninu ijọ irapada maa n pe ni "Pastor Dee tabi PD".
Iṣẹ ti olooogbe ọhun yan laayo ni iṣẹ alufa, akọrin ẹmi ati olukọ awọn ọdọ fun igbe aye to dara.
Dare, nigba aye rẹ maa n kọ awọn ọdọ ijọ naa bi wọn ṣe le di adari lọjọ iwaju ninu gbogbo ohun ti wọn ba n ṣe, paapaa ninu ijọ RCCG.
O ti fi igba kan ri ṣiṣẹ gẹgẹ bii Pasitọ lori ijọ RCCG House of Praise, to wa ni Birmingham, nilẹ Gẹẹsi.
Bẹẹ naa lo tun ṣiṣẹ gẹgẹ bii pasitọ ijọ naa, ẹka ti awọn ọdọ to wa ni Ipinlẹ Kaduna.
Ki ọlọjọ to de, oun ni pasitọ gbogbogbo fun awọn ọdọ ni RCCG fun ẹkun Niger, Benue, Kwara, Kogi, Nasrawa, Plateua ati Abuja.
Bakan naa, o ti di ipo mu gẹgẹ bi oludari gbogbo eto awọn ọdọ ni ijọ RCCG, alaga igbimọ eto ọdọọdun fun ayẹyẹ ọjọ ibi Pasitọ Adeboye (Marathon Messiah's Praise), eto ipagọ awọn ọdọ ẹkun ariwa Naijiria.
Gbogbo eleyii fun un ni anfani lati ni imọ kikun nipa awọn ọdọ kaakiri agbaye ati bo ṣe le mu ijọ maa dagba soke.
Orukọ iyawo rẹ ni Temiloluwa Adeboye, Ọlọrun si fi ọmọ ta awọn mejeji lọrẹ.
Àwọn èèkàn àgbáyé tó ń bá Bàbá Adeboye kẹ́dùn ikú ọmọ rẹ̀
Aarẹ Muhammadu Buhari ati awọn eekan lorilẹede Naijiria ti fi ọrọ ibanikẹdun ranṣẹ si adari ijọ Redeem, Pasitọ Enoch Adeboye to padanu ọmọ rẹ, Dare Adeboye.
Apapọ ẹgbẹ awọn ọmọ Pasitọ ninu ijọ Redeem sisọ loju rẹ pe Oluwadamilare Temitayo Adeboye jade laye lọjọ̣ Iṣ̣ẹ̣gun, Ọjọ̣ Kẹ̣rin, Oṣ̣u Karun, ọ̣dun 2021.
Amọ, ko tete han si awọn eniyan titi di owurọ Ọjọbọ, ti awọn eniyan si ti bẹrẹ si ni fi ọrọ ibanikẹdun ranṣẹ si ẹbi ati ara oloogbe naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Sunday Igboho, dẹ́kun ariwo fún ìyapa Nàíjíríà - YAF
- Buhari, Osinbajo, Atiku bá Bàbá Adeboye kẹ́dùn ikú ọmọ rẹ̀
- Wo ọjọ́ gangan tí Pásítọ̀ Dare Adeboye ti jáde láyé, ẹgbẹ́ àwọn ọmọ Pásítọ̀ RCCG kéde
- Èèyàn kan kú nínú ìjà tó n wáyé ní Mile 12 láti bíi ọ̀sẹ̀ kan
- NECO gbé èsì ìdánwò ọdún 2020 jáde!
- Ganiyu fẹ́ na pápá bora lẹ́yìn tó gún ìya ìyàwó rẹ̀ lọ́bẹ pa lọ́sàán àwẹ, ọwọ́ bá tẹ̀ ẹ́
- Ṣé o mọ àwọn òrìṣà ìṣẹ̀mbáyé méje tó di ilẹ̀ gbogbo àgbáyé mú?
- Àwọn agbébọn tún ti jí ènìyàn tó lé ní 100 gbé lọ ní Nàìjíríà
Aarẹ Buhari ninu atẹjade to fi lede loju opo Twitter ba gbogbo ẹbi, ara ati ijọ Redeem kẹdun lori ipapoda Pasitọ Dare Adeboye.
Bẹẹ si ni Buhari gbadura fun ẹbi oloogbe pe ki Ọlọrun fun wọn ni ẹmi lati gba ajaga naa ati wi pe ki wọn mọkanle nitori wọn yoo ri ara wọn ni ọjọ ajinde ni ikẹyin.
Bakan naa ni Igbakeji Aarẹ, Yemi Osinbajo ati Gomina Ipinlẹ Ogun, Dapo Abiọdun ṣe abẹwo si Pasito Adeboye ati Mummy G.O lati ba wọn kẹdun ọmọ wọn to di oloogbe.
Awọn mejeeji wa gbadura pe iranti oloogbe naa yoo ni ibukun.
Ninu ọrọ ibanikẹdun rẹ, oludije sipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu PDP, Atiku Abubakar gbadura fun awọn ẹbi oloogbe naa ki Olorun wa pẹlu wọn, ko si saanu fun wọn.
Bakan naa ni ọmọ ijọ Redeem, Eniola Akinkuotu ni ọjọ ti pasitọ Adeboye padanu ọmọ rẹ ni wọn kọ ọ si inu iwe adura ijọ naa, Open Heaven lati gbadura fun awọn ọmọ wọn.
Awọn ọmọ ijọ naa to ni iku rẹ dun awọn pupọ, ṣe apejuwe pasitọ Dare Adeboye gẹgẹ bi onirẹlẹ ọkan, ti o ma n gbadura ki Ọlọrun wa pẹlu rẹ ''God Bless You'' ni gbogbo igba.
Wọn tun ṣe apejuwe rẹ gẹgẹ bi olukọ ọrọ Ọlọrun to yanju ati aladura ti kii fi ọrọ awọn ọmọ ijọ rẹ ṣere nitori o ni ifẹ wọn denu.
Bakan naa ni wọn sapejuwe asiko yii gẹgẹ bi asiko idanwo igbagbọ nla fun Pasitọ Adeboye ati iyawo rẹ pẹlu adura wi pe ki Ọlọrun fun wọn ni agbara lati bori adanwo naa.