Pastor Adeboye: Ìyàwó Adeboye ní ó jẹ́ okùnrin tí gbogbo obìnrin fẹ́ràn láti fi ṣe ọkọ

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Iyawo pasitọ Enoch Adeboye, Foluke Adeboye ti sapajuwe ọkọ rẹ gẹgẹ bi ọkunrin akinkanju ti gbogbo obinrin fẹran lati fi ṣe ọkọ.

Foluke Adeboye sọ bẹẹ ni oju ọpọ ikansiraẹni Twitter rẹ lasiko ti wọn ṣe ayẹyẹ pasitọ Adeboye to pe ẹni ọdun mọkandinlọgọrin.

Pasitọ Adeboye ni adari ijọ irapada, The Redeemed Christian Church of God kaakiri gbogbo agbayẹ.

Pasitọ Foluke ni Ọlọrun nigba to n ṣẹda Enoch Adeboye ni nkan bi ọdun mọkandinlọgọrin ṣẹyin ṣe ẹda rẹ fun oun Foluke gẹgẹ bi ade ori.

O ni Ọlọrun mọ wi pe oun nilọ akinkanju ọkunrin, ọba, alufaa, woli ati ọkunrin to nirẹlẹ to ṣe e mu yangan, ti pasitọ Adeboye jẹ.

''Adeboye, O da mi loju wi pe Ọlọrun da ẹ fun mi ni o''

''Mo dupẹ lọwọ rẹ fun ifẹ to fihan mi, emi naa si fẹran rẹ tọkantọkan.''

''Iwọ ni ọkunrin naa ti gbogbo obinrin fẹ fi ṣe ọkọ wọn, ti gbogbo ọmọ fẹ ko jẹ baba wọn''

Iyawo Adeboye gbadura fun ọkọ rẹ pe ki Ọlọrun da ẹmi rẹ si , ko si ṣe ọpọlọpọ ọdun laye.

Bakan naa lo gbadura wi pe ki ilera ati ọrọ kun igbeaye pasitọ Adeboye, ki awọn si gbepọ ni irẹpọ titi opin aye wọn.

Ọjọ Keji, Oṣu Kẹta ni Pasitọ Adeboye to jẹ adari ijọ irapada, The Redeemed Christian Church of God pe ẹni ọdun mọkandinlọgọrin.