Ẹ wo èrò àwọn ènìyàn lórí bí Gòmìná Akeredolu ṣe fòfin de NURTW, RTEAN nípínlẹ̀ Ondo

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Awọn ọmọ Naijiria lori ayelujara ti fi ero wọn han lori igbeṣẹ Gomina ipinlẹ Ondo, Akeredolu to fofin de ẹgbẹ awọn awakọ, NURTW ati RTEAN nipinlẹ Ondo.

Ijọba ni awọn adari ẹgbẹ NURTW pẹlu ki wọn kuro ni awọn ibudokọ kaakiri ipinlẹ naa.

Bakan na ni wọn paṣẹ wi pe wọn ko gbọdọ gba owo lọwọ awọn awakọ Taxi tabi awọn ọlọkada mọ nipinlẹ naa.

ọpọlọpọ awọn to sọrọ nipa igbeṣẹ gomina naa gboriyin fun Gomina Akeredolu lori igbeṣẹ naa.

Wọn ni igbeṣẹ akọni ni, to si yẹ ko ti waye fun ọpọlọpọ ọdun sẹyin.

Bakan naa ni awọn kan kesi awọn gomina ni ipinlẹ Ogun, Oyo, Osun ati ipinlẹ Eko lati wo awokọṣe gomina ipinlẹ Ondo.

Amọ, awọn kan ni igbeṣẹ ijọba naa ko lee pe nitori wọn ko ṣe alakale ọna miran fun awọn ti wọn gbegile ọna iṣẹ ounjẹ oojọ wọn.

Bakan naa ni awọn miran bu ẹnu atẹ lu ijọba ipinlẹ Ondo wi pe igba wọn ma n lo awọn ẹgbẹ NURTW fun eto oṣelu ti wọn si wa da wọn nu ni saa keji nitori wọn ko nilo wọn mọ.

Awọn miran tun sọ wi pe iwa ọdaran yoo gbinlẹ si ni ipinlẹ naa nitori awọn ti wọn yọ ni ẹgbẹ naa, ko ni ri iṣẹ ṣẹ.

Akeredolu fòfín de NURTW àti RTEAN ní ìpínlẹ̀ Ondo

Ijọba ipinlẹ Ondo ti da iṣẹ ẹgbẹ awọn awakọ, NURTW, ati ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ awakọ, RTEAN duro ni ipinlẹ naa.

Olubadamọran pataki fun gomina Rotimi Akeredolu, Ọmọwe Doyin Odebowale sọ pe idaduro naa yoo bẹrẹ lẹsẹkẹsẹ.

Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ nile ijọba to wa niluu Akure, Odebowale ni igbesẹ naa ko ṣẹyin rogbodiyan to waye laipẹ yii lẹyin ti wọn fiku owo ọkọ takisi.

Odebowale sọ pe ki awọn adari NURTW ati RTEAN fi gbogbo ibudokọ to wa ni ipnlẹ naa silẹ ni kiakia.

Bakan naa lo tun paṣẹ pe ki awọn takisi pada si iye owo ti wọn n gbe awọn ero tẹlẹ, ti n ṣe ₦50 dipo ₦100 ti wọn n gbe ero ọkọ bayii.

Amugbalẹgbẹ gomina ọhun fi kun pe ijọba ipinlẹ Ondo ko ni gba ki ẹnikẹni fi aye ni awọn ara ilu lara.

O fi kun awọn agbofinro ti wa ni ikalẹ lati fi ṣikun ofin mu ẹnikẹni to ba tapa si aṣẹ tuntun naa ti ijọba ṣẹṣẹ pa.

Ṣaaju ni awọn awakọ takisi ipinlẹ Ondo, paapaa niluu Akure ti kọkọ ṣe afikun iye owo ọkọ ero lati ₦50 si ₦100, lẹyin ti ijọba kede owo tikẹti tuntun kan.

Eyii to mu ki awọn awakọ takisi naa ṣe afikun iye owo ọkọ, eyii ti ko dun mọ awọn eeyan ilu ninu.

Odebowale ti wa sọ pe ọwọ ijọba ni awọn awakọ yoo ti maa ra tikẹti bayii, kaka ki wọn maa ra lọwọ awọn oṣiṣẹ NURTW.