BBC Ethiopia, Tigray: Wọ́n ti tú akọ̀ròyìn BBC, Girmay Gebru sílẹ̀ kúrò látìmọ́lé ní Tigray

Wọn ti fi akọroyin BBC ti awọn ọmọ ogun to wa ni agbegbe Tigray, lorilẹ-ede Ethiopia fi si ahamọ tẹlẹ silẹ.

Wọn tu Girmay Gebru silẹ bayii.

Wọn mu u ni ọjọ Aje ti wọn si mu Girmay lọ si ipagọ awọn ọmọ ogun ki wọn to gbe e lọ si agọ ọlọpaa abẹle lọjọ Iṣẹgun.

Ni agọ ọlọpaa yii si lo sun si di ọjọ keji rẹ.

BBC ti bẹrẹ igbesẹ iwadii ohun to ṣokunfa atimọle yii ati abajade rẹ nilana ofin.

Bawo lo ṣe kọkọ ṣẹlẹ ṣaaju?

Iléeṣẹ́ ọmọ ogun ti fi akọ̀ròyìn BBC kan sí àtìmọ́lẹ́

Awọn ọmọ ogun to wa ni agbegbe Tigray, lorilẹ-ede Ethiopia ti fi akọroyin BBC kan si ahamọ.

Wọn ti akọroyin naa, Girmay Gebru, to n ṣiṣẹ fun BBC News Tiggrinya mọle pẹlu awọn eeyan mẹrin miran ni Makelle.

Awọn ti ọrọ naa ṣoju wọn sọ fun BBC pe, awọn ọmọ ogun ọhun fi ṣikun ofin mu awọn eeyan marun un kan, ti wọn si wa wọn lọ ni u ọkọ kan.

Bo tilẹ jẹ pe a ko le sọ eredi ti wọn fi ti awọn eeyan naa mọle, iroyin to tẹ wa lọwọ ni pe awọn ọmọ ogun naa ti gbe akọrọyin BBC ti mọle.

Lati oṣu kọkanla ọdun 2020 ni agbegbe Tigray yii ti wa ni iṣakoso ileeṣẹ ọmọ ogun Ethiopia lẹyin ti olori ijọba Abiy Ahmed kede pe awọn ti gba agbegbe naa pada lọwọ awọn ẹgbẹ alatako, Tigray People's Liberation Front, TPLFG.

Rogbodiyan to waye nibẹ lagbara sii lẹyin ti TPLF gba iṣakoso awọn agbegbe kan ti ileeṣẹ ọmọ ogun n ṣakoso rẹ ṣaaju.

Ọpọ ẹmi lo ti ba iṣẹlẹ naa lọ, ti ẹgbẹgbẹrun eeyan si ti di alairilegbe.

Atimọle akọroyin BBC yii lo n waye lẹyin ti awọn ologun naa ti kọkọ ti awọn eeyan meji to n ṣiṣẹ fun ileeṣẹ iroyin Agence France-Presse, AFP, ati Financial Times mọle.