Woman, Ethiopia's Tigray crisis: Ọmọbìnrin ọdún 18 ṣàlàyé bí ó ti gé lọ́wọ́ nígbà tí sọ́jà kan fẹ́ fipá bá a lòpọ̀

Akẹkọọbinrin orilẹede Ethiopia kan to jẹ ọmọ ọdun mejidinlogun ti ṣalaye bi o ti padanu ọwọ rẹ nigba ti o n wọya ija pẹlu sọja kan to fẹ fipa ba oun lopọ.

Akẹkọọbinrin naa ni sọja ọhun tun sọ fun baba baba oun lati fi ipa bóun lopọ.

Ọmọ ọdun mejidinlogun naa wa nile iwosan lẹkun Tigray nibi ti o ti n gbatọju fun bi oṣu meji bayii.

Ija ẹkun Tigray to bẹrẹ loṣu kọkànlá, ọdun 2020 ti ṣakoba fun igbe aye ọmọdebinrin naa at'awọn akẹgbẹ rẹ pẹlu ohun ti wọn fẹ jẹ laye.

Ọmọbinrin naa ṣalaye pe lọjọ kẹta, oṣu kejila ọdun to lọ ní sọja kan ṣaa deede wọle wa ti o sí beere ibi t'awọn jagunjagun Tigray wa.

Nigba ti o wa inu ile ti ko ri ẹnikan lo sọ fun baba baba mi pe ki o bami ni Ibalopọ.

Ọrọ yii bi baba baba ninu debi pe awọn mejeeji bẹrẹ si ni ja.

Akẹkọọbinrin naa ni sọja ọhun yinbọn fun baba baba oun ni ejika ati itan lẹyin lo pada sọ foun pe oun ti yinbọn pa a.

"O sọ fun mi pe ki n bọ aṣọ mi, mo bẹ ẹ ṣugbọn niṣe lo n lu mi bii bara.

A bẹrẹ si ni wọya ija titi ti inu buruku fi bi sọja ọhún eyi to jẹ ko doju ìbọn kọ mi ti o si yinbọn fun mi lapa nigba mẹta.

Bakan naa lo tun yinbọn fun mi lẹsẹ lẹẹmẹta ṣugbọn o kuro nigba to gbọ iro ibọn lati ita,"akẹkọọbinrin naa lo sọ bẹẹ.