You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Abia state university news: Àwọn agbébọn ti jí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ABSU gbé ní Abia
Afi bii ina to n ran, lẹyin ọjọ kan ṣoṣo ti awọn akẹkọọ to wa ni ahamọ ajingbe ni Kaduna moribọ, awọn agbebọn kan tun ti ji awọn akẹkọọ mii gbe ni ipinlẹ Abia.
Ninu atẹjade kan ti kọmiṣọna eto iroyin ipinlẹ naa, John Kalu, fi lede, o ni wọn ji awọn akẹkọọ naa, ti awọn ko tii mọ iye wọn gbe ni opopona Okigwe si Uturu.
O ni "gẹgẹ bii iroyin to tẹ wa lọwọ, awọn akẹkọọ naa n rinrinajo ninu ọkọ korope lati ilu Okigwe si Uturu laarin aago meje si mẹjọ alẹ ki wọn to ṣagbako awọn agbebọn ọhun lẹba igbo kan, ti wọn si ko awọn akẹkọọ naa lọ pẹlu awọn arinrinajo miran."
"Meji ninu awọn akẹkọọ naa moribọ ṣugbọn awọn to ku ṣi wa ni ahamọ awọn ajinigbe ti ko si sẹni to lẹ sọ ibi ti wọn wa."
Kalu fi kun un pe awọn n ṣiṣẹ papọ pẹlu ifọwọsowọpọ ijọba ipinlẹ Imo atawọn ẹṣọ alaabo ni ipinlẹ mejeji lati doola ẹmi awọn akẹkọọ ọhun.
Lẹyin naa lo rọ awọn akẹkọọ ati oṣiṣẹ fasiti naa lati fi ọkan wọn balẹ nitori awọn yoo rii daju pe wọn doola awọn akẹkọọ naa lai ku ẹnikan.
Ẹwẹ, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ ọhun ti sọ pe awọn ti bẹrẹ igbesẹ ti awọn akẹkọọ naa yoo fi di riri pada ni kankan.
Bi ẹ ko ba gbabe, ẹnu oṣu diẹ sẹyin ni ijinigbe awọn akẹkọọ di tọrọfọnkalẹ ni Naijiria, paapaa lagbegbe oke ọya.
Lọjọ kọkanla oṣu Kẹta ọdun yii, wọn ji akẹkọọ mọkandinlogoji gbe ni Federal College of Forestry Mechanization, to wa ni Afaka, ni ipinlẹ Kaduna.
- Ṣé o mọ àwọn òrìṣà ìṣẹ̀mbáyé méje tó di ilẹ̀ gbogbo àgbáyé mú?
- Àwọn agbébọn tún ti jí ènìyàn tó lé ní 100 gbé lọ ní Nàìjíríà
- Ọjọ́ 30 ni wọ́n fẹ́ fi gbé mi pamọ́, ariwo ọmọ ìjọ ló jẹ́ kí wọ́n tú mi sílẹ̀ - Father Mbaka
- Ẹ̀sùn gbígbìyànjú láti wọ́lé sí ojú ara ọmọdé pẹ̀lú ìpá àtàwọn ẹ̀sùn mìí tí Baba Ijesha yóò jẹ́ rèé
Nigba to di ogunjọ oṣu to kọja, wọn tun ji awọn akẹkọọ fasiti Greenfield gbe ni Kaduna yii kan naa.
Yatọ si Kaduna, wọn ti ji oniruru akẹkọọ mii gbe lawọn ipinlẹ bii Benue, Plateau, Katsina ati Zamfara.