You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ìdí ti àwọn obínrin fi yarí lori ìmọ̀ràn ti Adeboye gba àwọn ọkùnrin lóri igbéyàwó
Orí ayelujara yọ eruku laala lọ́sàn ọjọ́ Ìṣẹ́gun lẹ́yìn ti pásìtọ ijọ iràpada, (Redeemed Christain Church of God) Enoch Adeboye kéde pe ki àwọn 'ọmọ òun ọkùnrin' o ma fẹ́ obinrin ti ko ba mọ ina dá.
Bí àwọn kan ṣe ń gbósùbà káre fun baba Adeboye ni àwọn míran ni Baba ko sọrọ daada.
Nínú àwọn to sọ̀rọ̀ lòdi si ọ̀rọ̀ Baba Adeboye ni gbajugbaja sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀, Toke Makinwa.
Toke ni "iná sise ounjẹ kò si fún akọ tabi abo. Obinrin nikan kọ lo yẹ kó jẹ, ko yẹ ki ọkùnrin yan alábarin nítori ikùn rẹ, ti iyawo rẹ o ba mọ iná da ki ọkùnrin sisẹ takuntakun lati gba ẹni ti yoo maa dáná".
Yatọ si Toke Makinwa, ọ̀pọ̀ àwọn ọmọbinrin miran lori Twitter lo n binu pe ọ̀rọ̀ àye òde oni kìí ṣe nipa iná dida nìkan nítori pe , àti obinrin àti ọkunrin lo jọ n ṣe iṣẹ́ bákan náà.
Lẹ́yìn ti Baba Adeboye sọ ọ̀rọ̀ náa ni Twitter gbana ti ọ̀pọ̀ si gbàgbọ́ pé ẹni àtijọ ni baba náà to si jẹ́ pé ọ̀rọ̀ àye àtijọ ni o n sọ.
Ìgbà àkọ́kọ́ kọ́ nìyíì tí ọ̀rọ̀ Àlùfáà Adeboye dá àríyànjiyàn sílẹ̀ lórí ayélujára nítorí ìwáàsù rẹ̀.
Lọ́dún 2018, O sọ fún àwọn pásítọ̀ ìjọ̀ rẹ̀ pé wọ̀n ó sọ fún àwọn ọmọ ìjọ wọn pé "ẹnikẹ́ni tí kò bá kí n san ìdámẹ́wàá rẹ̀, kò ní lọ sí ọ̀run".
Bákan nàá ló ti sọ̀rọ̀ rí lọ́dún 2019 pé àwọn ọmọbìnrin kò gbọdọ́ fẹ́ ọkùnrin tí kò bá níṣẹ́ lọ́wọ́. Níbi ìsìn ọjọ́ Aiku kan ló ti sọ bẹ̀ẹ̀ l'ósù Karùn, ọdún nàá.
O sọ pé fífẹ́ irú ọkùnrin bẹ̀, yóò sọ obìnran nàá di 'iṣẹ́'.
Àti pé kò burú tí obìnrin bá bèérè lọ́wọ́ ọkùnrin tó fẹ́ ẹ́ fẹ pé "ṣé ó níṣẹ́ lọ́wọ́".
- Ọ̀gá àgbá ọlọ́pàá pàṣẹ pé kí wọn ṣàwárí àwọn pásítọ̀ tí wọn jí gbé
- Èmi kìí se Ọlọ́run, ẹ yé lo fọ́tò mí fún ẹ̀bùn - Adeboye
- Ọlọ́pàá Ogun dóòlà àwọn ọmọ ìjọ Redeem mẹ́rin tó kù lọ́wọ́ ajínigbé
- Òkété bórù mọ afurasí tó gbé àdó olóró wọ ilé ìjọsìn Winners ní Kaduna
- 'Street Gospel' tí mò ń kọ, Ọlọ́run ń fi tún ayé àwọn 'Boys' ṣe gan - Testimony Jaga
Ẹ̀wẹ̀, l'ọ́dún 2016, ó gba àwọn ọkùnrin ní ìmọ̀ràn pé obìnrin tí kò bá le gba àdúrà fún ó kéré tán, wákàtí kan.
Láìpẹ́ yìí nà ni awuyewuye gba ìgboro nígbà tó sọ ìdí tó fi sọ fún ọmọ rẹ̀ ọkùnrin láti gba ìṣẹ́ lọ́wọ́ akọ̀wé rẹ̀.
Èyí kò ṣẹ̀yìn bí ọmọ rẹ̀ ṣe sọ fún pé ara òun maa n ṣe bakan ti òun ba ti ri ọmọbinrin naa.
Ọpọlọpọ lo tako o pe o yẹ ki ọkunrin naa o le ko ara rẹ ni ijanu. Ati wi pe ko yẹ ki obinrin kankan o padanu iṣẹ rẹ nitori pe ọga rẹ ko le ko ara rẹ ni ijanu.
Biotilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ Naijiria si n tọpaṣẹ àtijọ laifi ti ọ̀laju ṣe bi ti awọn òkè òkun , wọ́n sì gbàgbọ́ pé inú ilé ìdána ni ààye to ṣe pàtàkì jùlọ fún obinrin ti ọkùnrin yóò si ma mú owó wálé.