RCCG: Ọlọ́pàá Ogun dóòlà àwọn ọmọ ìjọ Redeem mẹ́rin tó kù!

Ìròyìn tó ń tẹ̀ wa lọ́wọ́lọ́wọ́ ní wí pé gbogbo awọn ọmọ ijọ Redeem maraarun tawọn ajinigbe ji gbe ni Ijebu Ode ti gba itusilẹ lonii.

Iroyin to tan ka lana ni wi pe lójúnà ìrìnàjò wọn lọ síbi ìpàdé àdùrà níbi ìpàgọ́ ńlá RCCG ni wọn ti bọ́ sí ọwọ awọn ajinigbe ọhun.

BBC Yoruba kan si alukoro ile iṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbola Oyeyemi to fi aridaju han pe lootọ ni awọn ti doola ẹmi gbogbo wọn.

Lowurọ ni wọn kọkọ gba arabinrin kan ṣoṣo ti o wa laarin wọn silẹ pe awọn si n ṣe iṣẹ lati gba awọn to ku naa silẹ.

Nbayii, awn lpaa ti n ko gbogbo wn lọ si olu ile iṣẹ wn ni Abeokuta nibi ti wọn yoo ti ba awọn oniroyin sọrọ fun ẹkunrẹrẹ.

Abimbola Oyeyemi jẹ ko di mim pe ati ri awn mẹrin to ku doola ko dẹrun tori bi awọn ọlọpaa ṣe n ri wn ko kuro ninu igbo lawọn ajinigbepa ọhun naa n gbiyanju ati doju kọ wọn.

Ẹwẹ, alukoro ọlọpaa Ogun jẹ ko di mimọ pe awọn ti n ko awọn ti n ko wọn lọ si olu ile iṣẹ awọn bayii fun abo to daju ati lati fi ẹkunrẹrẹ ọrọ fun awọn oniroyin.