You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Testimony Jaga sọ ohun tójú rẹ rí kó tó lè wo ara rẹ̀ láwòdúpẹ́
"Kí n máa kọrin Ọlọ́run láàrín àwọn amugbó pé mi ju kí wọ́n pè mí sí ìsọjí ńla lọ".
BBc Yoruba ba akọrin ẹ́mi ti ọpọlọpọ mọ si Testimony Jaga lalejo nile orin rẹ.
Jaga kẹnu bọrọ, ko fẹ tan mọ tori itan igbesi aye rẹ ko to de ibi to yanju fọwọ tọ ni lọkan gan.
- Ìyàwó ilé lu ọmọ ìyàwó àkọ́kọ́ ọkọ rẹ̀ pa ní ìpínlẹ̀ Ogun
- Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ti mú Okada 188 pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ Maruwa 78 l'Eko
- Ọmọ ìjọ 20 kú bí wọ́n ṣe tẹ̀ wọ́n pa níbi ìsọjí ìtagbangba
- RCCG: Pásítọ̀ Adeboye ṣáájú ìwọ́de àdúrà CAN lòdí sí ìpànìyàn ní Nàìjíríà
- Akẹ́kọ̀ọ́ ọmọ Afíríkà kan tí lùgbadì ààrùn Coronavirus ní Fásitì China
"Ìdíle olórógún lórí mi yàn nígbà tí mo dé ayé. Ìyawó mẹ́fa, àwa ọmọ 27, láàrín wọn ni mo ti jáde".
Jaga ni ipo kejilelogun loun wa ninu awọn ọmọ baba oun. O ni "ìyá mi kò rí mi bí lásìkò tó yẹ kí ó bi mi, Ọ̀tá mi tún kú lọ́jọ́ ìkómọ fún wákàtí mẹ́jọ".
"Mo ti kó sọ́wọ́ Ọlọ́pàá lọ́pọ̀ ìgbà, SARS, Area G ...iya mi nikan lo maa n wa lẹyin mi ni gbogbo igba titi ti Ọlọrun fi ṣeyanu ko to di pe awọn oniroyin gbe mi saye".
Ohun ti Jaga la kọja lo jẹ ko sọ fun Ọlọrun pe bi o ba le ko oun yọ ninu iṣoro, oun a sin in.