You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Uganda Election Day 2021: Ídìbò Ààrẹ bẹ̀rẹ̀ ní Uganda lẹ́yìn tí ìjọba ti ìtàkùn àgbáyé pa
Idibo Aarẹ Uganda ti bẹrẹ laago meje aarọ oni lorilẹ-ede naa, iyẹn, aago mẹrin aarọ ni Naijiria, ṣugbọn o ṣeṣe ki esi idibo naa má jade titi di ọjọ Aiku.
Ọkan pataki lara awọn alatako Aarẹ Yoweri Museveni, to ti n tukọ ijọba orilẹ-ede naa bọ lati ọdun 1986, ni Bobi Wine to jẹ ẹni ọdun mejidinlogoji.
Bobi wine ni oun fẹ di Aarẹ lati ṣoju awọn ọdọ orilẹ-ede naa, nigba ti Museveni sọ pe oun n dupo fun sa kẹfa fun itẹsiwaju orilẹ-ede naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Irú ẹ̀dá wo ni Lamidi Adeyemi? Aláàfin tó rí ìbẹ̀rẹ̀ àti opin sáà gómìnà mọ́kànlélógún l‘Oyo
- Àwọn olorì Aláàfin fi oríkì awúnilórí yẹ́ ọkọ wọn sí fún àádọ́ta ọdún tó gorí ìtẹ́
- Àwọn onílù mí ló ń tú àṣírí ìkà èèyàn tó bá wọ ààfin mi - Aláàfin
- Bí Gómìnà Makinde bá ṣẹ̀ mí, lẹ́tà lásán ló jẹ mí- Aláàfin Ọ̀yọ́
- Ọba Lamidi Adeyẹmi, òṣìṣẹ́ adójútòfò àti Abẹ̀ṣẹ́kùbíòjò kó tó jọba
- Àwọn onílù mí ló ń tú àṣírí ìkà èèyàn tó bá wọ ààfin mi - Aláàfin
- Eyí ni àwọn arẹwà 'ẹ̀lẹ̀ Daddy', àfẹ́fẹ́ tí Aláàfin fi ń mí
- Wò ó bí Alaafin àti aya àkọ́fẹ́ rẹ̀, Olorì Abibat ṣe pàdé ní èwe
- Àwọn alálẹ̀ kò ní forí jìn mí tí ń kò bá ṣe ọdún Ṣàngó - Alaafin
- Àwọn kókó ohun tó wà nínú lẹ́tà tí Aláàfin kọ sí Fayemi rèé
Ṣaaju idibo naa ni oriṣiriṣi rogbodiyan ti n waye, ti ẹmi awọn kan si ti ba awọn iṣẹlẹ naa lọ.
Lara awọn iṣẹlẹ naa lo mu ki ijọba ilẹ naa ti gbogbo oju opo ibanidọrẹpọ ati ikansiraẹni bii Facebook ati WhatsApp pa, ṣugbọn ọpọ awọn eeyan kaakiri ilkẹ adulawọ n lọ ami #UgandaDecides2021 lati sọrọ lori idibo naa.
Nigba to n sọrọ lori idi ti wọn ṣe ti awọn oju opo naa pa, ijọba Uganda sọ pe igberaga ati ẹtanu ileeṣẹ Facebook ti pọ ju lo jẹ ki wọn bẹgi dina oju opo awọn to n lo nilẹ ọhun.
- Ọ̀dọ́ Bauchi ṣe àríyá ìbálòpọ lẹ́yìn tí àpèjẹ oníhòòhò forí ṣánpọn ní Kano
- Èèyàn mẹ́sàn án kú, 1,398 míràn tún lùgbàdì Coronavirus ní Nàìjíria
- Ìdí mẹ́fà rèé tí Instagram, Facebook le fi wọ́gilé ojú òpó ìkànsíraẹni rẹ
- Wo àsọdùn ìròyìn tíléeṣẹ́ ìròyìn òkèèrè gbé lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ìjínigbé akẹ́kọ̀ọ́bìnrin Nàìjíríà
Ṣaaju ni Facebook ti kọkọ ti oju opo to jẹ ijọba ilẹ ọhun pa nigabti idibo naa n sun mọ etile.
Ẹwẹ, irọlẹ ọjọ to kangun si ọjọ idibo ọhun ni ijọba yii kan naa ti itakun agbaye pa patapata lorilẹ-ede ọhun.
Wo kókó mẹ́rìnlá nípa Ààrẹ tó ń du ipò fún sáà kẹfà lẹ́yìn ọdún 35 lóri oyè
Yoweri Museveni jẹ ọkan pataki lara awọn oloṣelu orilẹ-ede Uganda, oun si ni Aarẹ orilẹ-ede naa lati ọdun 1986.
O wa lara awọn to kopa ninu iditẹgbajọba to yẹ aga ijọba mọ Aarẹ Idi Amin ati Milton Obote nidii laarin ọdun 1980-1985.
Lọwọ lọwọ bayii gẹgẹ bi oludije fun ipo aarẹ nilẹ Uganda, Museveni ti gbe awọn oju opo ibanidọrẹpọ ati ikansiraẹni lori ayelujara ti pa nitori ibo aarẹ to n bọ lna lorilẹede naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ẹlẹ́tàn ni ọkùnrin, tó bá rí nkan tó n wa lára obìnrin, yóò yí ìwà padà - Bimpe Oyebade
- Ìdí tí àwọn èèyàn kan kò fí le ni àrùn Coronavirus
- Wo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ Trump tó mú kí alátakò ilé darapọ̀ mọ́ tìta láti yọ nípò
- A kò le gbà kí ASUU gba ₦30bn nínú ₦40bn tíjọba gbé kalẹ̀ - NASU yarí
- Ẹ̀yin adarí Nàíjíríà, ẹ dẹ́kun àwáwí asán lórí ètò ààbò tó mẹ́hẹ - Ààrẹ àṣòfin àgbà
- Ẹ dákẹ́ àhesọ ọ̀rọ̀, ohun tó pa ẹ̀gbọ́n àti àbúrò Orisabunmi rèé - Mọ̀lẹ́bí gbarata
- Wo àdánù tó wà nínú gbígba ayédèrú áápù fún ìforúkọsílẹ̀ NIN lórí ayélujára
- Àmúlò ẹ̀rọ POS fun òwò ṣíṣe, ṣé ó tọ̀nà nínú Islam àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?
- "Ẹ̀yin tẹ̀ ń parọ́ ẹlẹ́yà-mẹ̀yà mọ́ Amotekun Oyo, Seyi Makinde lẹ̀ ń dojú ìjà kọ"
- Kí ló ma n fa Àkúfà nílẹ̀ Yorùbá, àti ọ̀nà àbáyọ?
Bakan naa ni aarẹ Museveni ti n naka aleebu soju opo Facebook pe o n se igberaga lasiko toun pasẹ fun lati gbegi dina oju opo awọn ọmọ Uganda to n lo Facebook saaju ibo aarẹ.
Museveni, ẹni to wọ asọ ologun lasiko to n bawọn eeyan orilẹede rẹ sọrọ lori mohunmaworan orilẹede naa, ti orilẹede Amẹrika si ti bu ẹnu atẹ lu igbesẹ aarẹ ọhun.
Amẹrika ni gbe idi dina oju opo awọn araalu nitori idibo tako ẹtọ ọmọniyan ti wọn ni labẹ ofin.
Nibayii orilẹede Amẹrika ti ni oun ko ni fi awọn onwoye ibo lati ilẹ okeere ransẹ si ilẹ Uganda lasiko idibo aarẹ to n bọ lọjọbọ ọsẹ yii.
Amẹrika ni ida marundinlọgọrin awọn onwoye ibo lati ilẹ Amẹrika ni ajọ eleto idibo lorilẹede Uganda kọ lati fi orukọ wọn silẹ fun itọpinpin ibo naa.
Gẹgẹ bi Natalie Brown tii se asoju ilẹ Amẹrika si Uganda ti salaye, ajọ eleto idibo naa ko sọ idi ti eyi fi ri bẹẹ.
Diẹ lara bi irinajo aye aarẹ Museveni ṣe lọ ree, ko to de ipo aarẹ ati lẹyin rẹ:
- Wọn bi Museveni lọjọ karundinlogun, oṣu kẹjọ, ọdun 1944 ni Ntungamo, Uganda
- Orukọ abisọ rẹ ni, Yoweri Kaguta Tibuhaburwa Museveni, orukọ baba rẹ si ni Yoweri Kaguta Museveni nigba ti iya rẹ n jẹ Esther Kokundeka
- Museveni í iyawo kan ṣoṣo to fẹ lọdun 1973, obinrin naa si bi ọmọ mẹrin fun
- Aarẹ naa kawe gboye ni fasiti Es Salaam, to wa ni Tanzania nipa eto eto iṣowo lọdun 1970
- Ni 1970 yii kan naa ni Museveni pada sorilẹ-ede rẹ lati ṣiṣe pẹlu olori ijọba lọdun naa lọhun, iyẹn Milton Obote
- O lọ ṣatipo ni Tanzani lẹyin ti Idi Amin gba ijọba mọ Obote lọwọ, asiko kan naa lo da ẹgbẹ ọlọtẹ FRONASA silẹ pẹlu afojusun lati yẹ aga mọ Idi Amin nidii
- Ni oṣu Kẹrin ọdun 1979, ẹgbẹ FRONASA yẹ aga mọ Idi Amin nidii, eyii to gbe Museveni si ipo to ga ninu ileeṣẹ ologun ninu ijọba tuntun naa
- Laarin 1979 si 1980, oun ni minisita eto abo fun ilẹ Uganda
- Nigba to di ọjọ kẹrindilogun, oṣu Kinni, ọdun 1986, Museveni gba ijọba lọwọ ijọba ologun ti ọgagun Tito Okello n tukọ rẹ
- Lẹyin ọdun mẹwaa lori oye, wọn dibo yan Museveni gẹgẹ bi Aarẹ lẹẹkan si loṣu Karunn un ọdun 1996
- Lọdun 2001, 2006, 2011 ati 2016 ni wọn tun yan Museveni si ipo gẹgẹ bii Aarẹ Uganda
- Lọdun 2014, o buwọlu abadofin kan to tako ibalalopa laarin akọ si akọ ati abo si abo
- Ni ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹjọ ọdun 2019, akẹkọọ kan ni Fasiti Havard pe Museveni lẹjo pe o bẹgi dina oun lati má ri oun ti Museveni ba n fi soju opo Twitter rẹ
- Ni oṣu Kinni ọdun 2021, Museveni yoo du ipo Aarẹ fun saa kẹfa pẹlu awọn oloṣelu miran, ṣugbọn ẹnikan to lamilaaka ju laarin awọn alatako rẹ ni olorin takasufe to di oloṣelu, Bobi Wine, to jẹ ẹni ọdun mẹtadinlogoji
- Bakan naa lo ti gbe awọn oju opo ikansiraẹni lori ayelujara ti pa saaju eto idibo aarẹ to n bọ naa.