Alaafin: Ààyò mi, ọkùnrin tó rẹwà jùlọ àti kọ́kọ́rọ́ ọkàn mi wà lára ọ̀rọ̀ ìwúrí táwọn olorì fi kí Ọba Adeyemi

Bi aadọta ọdun ti Alaafin ilu Ọyọ, Ọba Lamidi Adeyẹmi Kẹta gori oye ṣe n kanlẹkun, oriṣiriṣi ikini ati ọrọ idunnu ni awọn olori laafin rẹ ti n fi sita.

Pupọ ninu awọn olori naa lo bọ sori ayelujara Instagram ati Facebook wọn, lati ki Kabiesi ku oriire, ti wọn si tun lo anfaani naa lati fi imọriri wọn han.

Ko si sẹni ti yoo ka ọrọ ikinni naa, ti ori rẹ ko ni wu nipa kiki ati kiki tawọn ayaba naa se, eyi to n yonbo Ọba Adeyemi.

Diẹ lara awọn olori to ki ọba Adeyemi ree ati ọrọ ikinni ti wọn fi n ki ọkọ wọn lawọn oju opo ayelujara wọn.

Ayaba Mujidat Adeyemi: Aayo mi ni Ọba Adeyemi

Ninu ọrọ ikinni tiẹ si Ọba Adeyemi, Ayaba Mujidat Adeyemi ni aayo oun ni Kabiyesi jẹ, ti yoo si ma a jẹ lailai.

O ki Kabiyesi lorukọ rẹ ati ti awọn ọmọ rẹ pe - Kabiyesi, Oba Nla, Oba to nfi Oba je, Oba to ngba idobale Oba, Alowolodu bi iyere, afinju Oba ti lo golu.

O wa gbadura pe ki Alaafin tubọ lo ọpọlọpọ ọdun lori itẹ awọn baba rẹ.

Ayaba Sulat Motunrayo Adeyemi: Ọkọ mi ni ọkunrin to rẹwa julọ

Ayaba Sulat Motunrayo Adeyemi sọ pe oun ati awọn ọmọ oun ba ọkunrin to rẹwa julọ, to jẹ oniwa jẹẹjẹ, ati ọlọyaya ku ayẹyẹ aadọta ọdun lori itẹ.

O ni Ade a pẹ lori yin, irukẹrẹ a pẹ lọwọ yin, igba ọdun, ao jọ ma lo igba ni."

Ayaba Memunat Adeyemi: Alaafin lo ni kọkọrọ ọkan mi lọwọ

Ayaba Memunat Adeyemi sọ pe, Akikanju ni Alaafin jẹ fun oun, ẹni to ni kọkọrọ to ṣi ọkan oun, ọkunrin pataki to ma n da oun lọrun ni gbogbo igba, ati baba awọn ọmọ oun.

O ni ọpọlọpọ ayọ ni Kabiyesi ti mu wọ aye oun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ayaba Folashade Adeyemi: Alekun ara ọkọ mi yoo maa pọ si

Ayaba Folashade sọ pe oun ki Kabiesi ku ayẹyẹ aadọta ọdun lori itẹ, o si gbadura ki alekun ilera ati okun pọ si fun baba.

Olori Damilola Adeyemi:

Ọrọ ikini ti Olori Damilola Adeyemi fi ranṣẹ si Alaafin yatọ diẹ si ti awọn akẹẹgbẹ rẹ.

O ni oun ni olori to jẹ oloriire julọ ni aafin Kabiesi, nitori pe wọn ko ti i bi oun nigba ti Alaafin jọba. Ṣugbọn oun ṣoriire pe oun jẹ ara awọn olori rẹ lasiko ayẹyẹ nla yii.

"Mo nireti pe olori rẹ ni ma a tun jẹ ti mo ba tun aye wa."

Ayaba Rukayat Abiodun Adeyemi: Baba to nifẹ ọmọ ati ọkọ to nifẹ aya ni Alaafin

Ayaba Rukayat Abiodun Adeyemi ṣapejuwe asiko Alaafin lori oye pe, o ti mu ọpọlọpọ ibukun, idagbasoke ati alaafia wa silu Ọyọ ati awọn ilu to wa ni abẹ rẹ.

"Baba lo jẹ fun mi, ọkọ to ni ifẹ aya, ati awokọṣe fun awọn ọmọ mi."

O gbadura pe ki Allah da ẹmi Kabiesi si ninu ọrọ ati ilera to peye, fun idagbasoke ilu Ọyọ ati agbagbe rẹ.

Wo ìdí tí Alaafin fi ṣún ayẹyẹ àádọ́ta ọdún tó gorí ìtẹ́ síwájú

Yoruba ni bi ọọdẹ ko ba dun, bi igbẹ nilu n ri, bi ilu ko ba si dun pẹlu, ko si ọmọ talaka ti yoo le rode ẹmu.

Bẹẹ lọrọ ri pẹlu isọri keji ọwọja ajakalẹ arun Coronavirus to tun gbode bayii, eyi to n se akoba feto ọrọ aje, to si tun n se idiwọ fun ọpọ ayẹyẹ ni sise.

Lọwọ lọwọ bayii, arun naa ti se idiwọ fun Alaafin tilu Oyo, Ọba Lamidi Olayiwola Adeyemi lati sami ayẹyẹ aadọta ọdun to gori itẹ awọn baba nla rẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ayẹyẹ naa, to yẹ ko bẹrẹ lonii ọjọ Aiku ni wọn ti kede pe ko ni le waye mọ nitori awọn idi kan to da lori bi ọwọja arun Covid-19 se n ja kiri ilu.

Bi o tilẹ jẹ pe eto lati sami ayẹyẹ aadọta ọdun ti ọba alaye naa gba ade, ti debi to lapẹrẹ, ti wọn si ti fi iwe pe ọpọ awọn eeyan jankanjankan lati peju sibi ayẹyẹ naa, sibẹ ayẹyẹ naa ko lee see se lasiko yii.

Atẹjade kan to wa lati aafin Oyo, ti Iku Baba Yeye funra rẹ fọwọsi salaye pe lootọ ni oun ti seto ayẹyẹ idupẹ alarinrin amọ oun fẹ tun ero oun pa lori igbasẹ naa.

"Pẹlu irora nla ninu ọkan mi ati aabo fun ẹmi eeyan, ni mo fi rọ awọn Oyomesi lori idi ta fi gbọdọ sun ayẹyẹ naa siwaju titi di ọjọ mii, ọjọ re, ti arun Coronavirus yoo kasẹ nilẹ.

Lara awọn idi ti mo si se gbe igbesẹ irora naa ni lati bọwọ fun ofin itakete sira ẹni pẹlu bi yoo se nira lati gbalejo lati ilẹ okeere , ti wọn si gbọdọ lo ọsẹ meji ni yara iseraẹnilọjọsi ki wsn fara kinra pẹlu ẹlomiran, eyi to le ma see se."

Alaafin wa kede pe aabo ẹmi awọn eeyan lo jẹ oun logun ju ayẹyẹ ki ayẹyẹ lọ, idi si ree ti oun ko fi ni se ayẹyẹ aadọta ọdun ti oun gba ade, ọlọsẹ kan ọhun mọ.