You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Alaafin: Ọ̀pọ̀ èèyàn ń bèèrè pé kí ló dé tí Olorì Badra kò fi sí nínú fọ́tò ọdún Ileya
Ọjọ Ẹti ni ọdun Ileya waye fọdun yii jakejado agbaye ti gbogbo idile si joko sile lati se ayẹyẹ ọdun naa papọ.
Bakan naa si ni ayẹyẹ yii waye ni aafin Ọyọ, nibi ti iku baba yeye, Ọba Lamidi Olayiwola Adeyemi atawọn olori rẹ ti se yata-yoto ọdun.
Asiko ti wọn n se ọdun yii ni Ọba Adeyemi ke si awọn olori rẹ lati wa fara kinra pẹlu oun ni gbọngan igbẹjọ.
Awọn ayaba kekere naa, ti wọn jẹ ẹlẹ Daddy ati afẹfẹ ti Alaafin fi n mi ni wọn rọgba yi baba ka, to si ya aworan pẹlu wọn.
Ninu aworan naa, ti awọn ayaba ọhun fi soju opo ayelujara wọn, ni apapọ awọn ẹlẹ Daddy naa ti jẹ meje, dipo mẹjọ taa mọ wọn mọ tẹlẹ.
Ẹni to ba si se akiyesi aworan naa finni-finni lati mọ ewo ninu awọn olori ni ko si ninu aworan naa, a ri pe Olori Badrat Olaitan Ajoke Adeyemi ni ko bawọn peju ya fọto lọjọ Ileya.
Ọna lati ba baba laafin se ayẹsi awọn olori naa si lo mu ka fi aworan naa soju opo Facebook wa.
- Kọ́ńdọ̀mù tó bẹ́ gbé iléèṣẹ́ ìjọba àti aládáni kan dé ilé ẹjọ́
- Ipa tí Fathia Balogun kó nínú bí mo ṣe dèèyàn lágbo òṣèré fíìmù Yorùba rèé - Baba Ijesha
- Èèyàn 16 kú lẹ́yìn tí bàálù Air India já lulẹ̀ , tó sì kán sí méjì ní Kerala
- Àgbáríjọ àwọn nọ́ọ̀sì fẹ́ gbé Olamide Baddo lọ sílé ẹjọ́ fún ìbanilórúkọjẹ́
- Inú odò ni wọ́n ti rí òkú ọmọ ọdún méjì tó sọnù l'ọ́jọ́ ọdún Eid nílùú Ibadan
Sugbọn iyalẹnu lo jẹ pe ibeere to gba ẹnu ọpọ ololufẹ Ọba Adeyemi lasiko ti wọn foju kan aworan naa ni pe:
Ki lo mu Olori Badra kuro l'Alaafin Oyo lọjọ Ileya, ti ko fi ba awọn ayaba yoku ya aworan pẹlu ọkọ wọn lọjọ ọdun?
Koda ọpọ ninu awọn eeyan yii lo tun n beere pe, abi tootọ ni iroyin to ja rain-rain nijooni pe, Alaafin ti le Olori Badrat jade kuro ninu aafin rẹ lori ẹsun asemase?
Bẹẹ ba si gbagbe, iroyin naa lo fẹsun kan Olori Badrat Olaitan Ajọke Adeyemi pe o n ni ifẹ ikọkọ pẹlu ọba olorin fuji kan, Alhaji Wasiu Ayinde Kwam 1.
Iroyin naa fikun pe, isẹlẹ ọhun lo mu ki Ọba Adeyemi ja okun ifẹ to wa laarin rẹ ati olori Badrat, to si ni ko jade kuro ninu aafin.
Bi o tilẹ jẹ pe Olori Badrat ati Wasiu Ayinde sẹ pe ahesọ ọrọ lasan ni iroyin naa, ofuutu-fẹẹtẹ, aasa ti ko ni kaun si ni pẹlu.
Amọ ko si atẹjade kankan to wa lati aafin Oyo lori isẹlẹ naa, ti ko si si ẹni to lee fidi rẹ mulẹ, boya Olori Badrat si wa ninu aafin abi o ti ko kuro.
Sugbọn ohun ti awa sakiyesi ni pe, Olori naa ko fi bẹẹ gbe aworan oun ati ọkọ rẹ, Alaafin soju opo ayelujara rẹ, gẹgẹ bo se maa n se.
Bakan naa, ko si ajọsepọ mọ laarin rẹ ati awọn olori Alaafin to ku loju opo ayelujara, gẹgẹ bi wọn ti maa n se tẹlẹ.
Bẹẹ si ni Olori Memunat Omowunmi Adeyemi ti oun ati Olori Badrat Olaitan dijọ jẹ korikosun ninu aafin gan, ni wọ̀n ko dijọ se bii ti atijọ mọ.
Asa awọn olori Alaafin ni pe ki wọn maa ki ara wọn ku ayẹyẹ ọjọ ibi tara wọn tabi ti ọmọ wọn.
Sugbọn lati igba ti isẹlẹ ọhun ti waye, ko si Olori Alaafin kankan to ki Ayaba Badrat ku ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ, ti oun naa ko si ki ẹnikẹni ninu wọn.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ọọ̀ni obìnrin, Lúwòó Gbàgídà rèé, akọni tó ń gun ọkùnrin ní ẹṣin rìn
- Ìtàn tó rọ̀ mọ́ òwe ‘aṣọ kò bá Ọ́mọ́yẹ mọ́...’ rèé
- MKO Abiola, iṣẹ́ aṣẹ́gità ló fi bẹ̀rẹ̀ okoòwò
- Iṣọla Oyenusi rèé, ẹnití ìfẹ́ obìnrin ṣun dé ìwà ìdigunjalè
- Taiwo Akinkunmi, ọmọ Ibadan tó ya àsìá Naijiria
- Ayinla Ọmọwura, orin èébú àti oríyìn lo fi di ọ̀rẹ́ àwọ̀n obìnrin
Boya lasiko ti ayẹyẹ ọjọ ibi wọn ba ko tabi tawọn ọmọ wọn, eyi to n kọ ọpọ onwoye lominu.
Idi si ree ti ọpọ eeyan tun fi n beere pe 'Nibo ni Olori Badrat Ajoke wa lasiko ọdun Ileya?