You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ọyọ: Alaafin bi ibeji l‘ẹẹmeji lọsẹ kansoso
Alaafin tilu Ọyọ, Ọba lamidi Ọlayiwọla Adeyẹmi kẹta ti bi ibeji ni ẹẹmeji ọtọọtọ laarin ọsẹ kansoso.
Bẹẹ ba si gbagbe, Ayaba Fọlasade Adeyẹmi ti bi ibẹta fun Alaafin lọdun diẹ sẹyin.
Ayaba Mẹmunat Adeyẹmi lo kọkọ bi ibeji obinrin meji ni ọjọ aje, ọjọ kọkandinlogun osu keji ọdun 2018 ti Ayaba Badrat Adeyẹmi naa tun fi ibeji ọkunrin meji lee lọjọ keje lẹyin ibeji akọkọ.
Ọjọ aiku, ọjọ karundinlọgbọn osu keji ọdun 2018, si ni Ayaba Badrat bi ibeji ọkunrin mejeeji naa.
Ọpọ eeyan si lo nya lẹnu pe Ọba Adeyẹmi to ti le ni ọgọrin ọdun si tun ni agbara lati bi ibeji ati ibẹta lọpọ igba, ti wọn si fẹ mọ asiri agbara Alaafin.
Nigba to nba ileesẹ BBC Yoruba sọrọ, ọmọbinrin Alaafin, Ọmọọbabinrin Olubunmi Labiyi ni inu ounjẹ ti baba oun njẹ ni asiri agbara rẹ wa.
Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:
O ni Alaafin kii jẹ ounjẹ amọga, bẹẹ ni kii mu ọti tabi ohun mimu ẹlẹrindodo, kii jẹ obi tabi mu kọfi, ti ko si tun kundun awọn ounjẹ oyinbo.
"Eso jijẹ ni asiri agbara baba mi. Alaafin maa njẹ eso bii ọgẹdẹ, to si tun maa njo daada. O loju ọdọ to lee tayọ baba mi to ba dọrọ jijo bata. Bẹẹni baba mi kii jẹun kiri ni ode"
Ẹ gbọ Ọmọọbabinrin Olubunmi Labiyi siwaju si: