Elon Musk: Owó rẹ jù àpapọ̀ owó Dangote àti àwọn èèyàn 19 míràn tó lówó jùlọ ní Áfíríkà

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ko si ani ani mọ,nilẹ toni to mọ yi, Elon Musk lẹni to lowo julọ lagbaye.

Owo rẹ gẹgẹ bi wọn ti ṣe ṣagbekalẹ rẹ ti re kọja biliọnu marundinlaadọwa dọla.

Ipo kini to ṣe pe Jeff Bezos to ni Amazon wa nibẹ tẹlẹ ti di ti Musk bayi iyẹn ẹni to ni ileeṣẹ ọkọ ẹlẹktriki, Tesla.

Yatọ si pe Musk jẹ olokoowo ọmọ ilẹ South Afrika, to si tun niiwe igbelu Canada ati Amẹrika, ki lawọn nkan miran to ṣe wi pe awọn eeyan ko mọ nipa rẹ?

Ni meni meji, awọn ohun to yẹ ki ẹ mọ nipa rẹ ree:

Apapọ owo awọn eeyan ogun to lowo julọ ni Afrika ko to ti Musk

Aliko Dangote Naijiria to jẹ ẹni to lowo julọ ni Afrika ati awọn olowo ẹgbẹ rẹ mi ko sunmọ owo Elon Musk.

Lọdun 2020, iwe igbadegba Forbes to maa n gbe orukọ awọn olowo jade sọ pe apapọ owo awọn eeyan ogun to lowo julọ ni Afrika lọdun 2020 ko ju biliọnu mẹtalelaadọrin le diẹ dọla lọ.

Owo Dangote to lewaju ninu wọn jẹ biliọnu mẹwa le diẹ dọla ti Nassef Sawiris ọmọ Egypt to tẹle si wa ni biliọnu mẹjọ dọla.

Mike Adenuga to ni ileeṣẹ Globacom lo wa ni ipo kẹta pẹlu biliọnu meje dọla le diẹ.

Abikẹyin rẹ ni orukọ tawọn eeyan ko mọ bi wọn yoo ṣe pe, X Æ A-12

Oju opo Twitter gbanajẹ ni ọdun 2020 lẹyin ti Elon Musk kede orukọ ọmọ ti oun ati akọrin Grimes ṣẹṣẹ bi.

Ọpọ eeyan lo ro wi pe Elon Musk n ṣwada ni nigba to sọ pe awọn yoo maa pe ọmọ naa ni X Æ A-12.

Eyi si mu ki ọpọ maa beere pe ki ni itunmọ orukọ yi ati pe bawo ni wọn yoo ṣe maa pe.

Iya ọmọ naa pada ṣalaye itunmọ orukọ naa loju opo rẹ ni Twitter.

Amọ ṣa ni ti yin tootọ awa gaan ko mọ bi a o ti ṣe pe orukọ naa.

Elon Musk ko gbagbọ pe lootọ ni Ajakalẹ Covid-19 wa

Lara awọn to sọrọ ti ko mu ọgbọn wa nipa Covid-19 ni Elon Musk wa.

Ọkan lara ohun to sọ ni pe nigba ti yoo ba fi di oṣu Kẹrin ọdun 2020, ko ni fẹ si eeyan ti yoo ni arun naa nilẹ Amẹrika.

Yatọ si eyi, ọpọ igba lo ti kọ si oju opo Twitter rẹ pe ki wọn ma ṣe iṣede tabi konileogbele nitori Covid-19.

Ninu ọrọ rẹ, fifi ofin de awọn eeyan ki wọn ma jade dabi ki eeyan maa ṣe ijọba amfipamuni.

O ta Pay Pal fun Ebay lọdun 2002 ni biliọnkan abọ dọla

Igba akọkọ ree ti Elon Musk yoo pa owo to to biliọnu dọla.

Saaju ki o to ta Pay Pal lo ti fi owo to pa nidi tita ileeṣẹ Zip2 lati fi da ileeṣẹ miran X.com silẹ.

X.com yi lo gbooro to fi wa da PayPal silẹ.

Bi a ba fi owo rẹ kọ 2nd Niger Bridge, afara 288.6 ni yoo jẹ

Nibi ti owo Elon Musk pọ de ti a ba ni ka fi kọ afara 2nd Niger Bridge ti ijọba Naijirira ti n kọ lati ọjọ yi, afara iru rẹ lọna 288.6 ni a o ri kọ.

Idi ni pe ti a ba se isiro iye owo afara naa tii ṣe 653 miliọnu dọla ta yọ kuro ninu owo Elon Musk tii ṣe 188.5 biliọnu dọla afara to fẹ ẹ to ọrinlenigba le mẹsan la o kọ ninu rẹ.