You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Contraband: Ọlọ́pàá Uganda rí ohun ìpara olóró nínú ‘baby’
Ile iṣẹ to n gbogun ti iwa gbigbe oogun oloro lọna aitọ wọle ti fi panpẹ ọba mu arakunrin to n gbe ohun ipara oloro si inu ‘baby’ onike.
Ọga Agba aṣọbode lorilẹ-ede Uganda, Dicksons Kateshumbwa lo ni arakunrin naa to gbe 'baby' pọn sẹyin ni ọwọ tẹ ni ibode Democratic Republic of Congo.
Dicksons Kateshumbwa ni oju opo twitter rẹ sọ wi pe awọn to n ṣisẹ fayawọ kii ye pa eniyan lẹrin.
Dicksons ni arakunrin ti ọwọ ba naa kọ ọpọlọpọ ohun ipara ati ọṣẹ iwe sinu ‘baby’ naa to si gbe e pọn bi ọmọ, ni ọna lati maṣe jẹ ki wọn fura si oun ti wọn gbe naa.
Ọga Agba aṣọbode lorilẹede Uganda ni awọn eniyan ma n gbe oṣẹ ati ohun ipara to n mu eniyan pọn fo wọlẹ lati ẹnu ibode DR Congo, eleyii ti awọn ti wọgile ni ọpọ igba.
Bakan naa lo fi lede pe ọdun 2016 ni awọn ti wọgile gbigbe ọṣẹ ipara borabora wọlẹ si orilẹ-ede naa, nitori o ni awọn ohun ipalara bi hydroquinone ati mercury to n ṣe ipalara fun ara.