Afcon Qualifiers: Àmì ayò 2-1 ni Naijiria fi ṣàgbà Benin Republic

Ikọ agbabọọlu Naijiria, Super Eagles, ti fi agba han ikọ Benin Republic ninu ifẹsẹwọnsẹ ipegede fun idije ifẹsẹwọnsẹ ilẹ Afirika.

Ifẹsẹwọnsẹ naa waye ni papa isere ni ilu Uyo, ni ipinlẹ Akwa Ibom.

Amọ ifẹsẹwọnsẹ naa ko kọkọ sẹnu ire fun Naijiria, nitori ikọ Benin Republic lo kọkọ gba bọọlu si awọn Naijiria ni isẹju mẹta ti ifẹsẹwọnsẹ naa bẹrẹ.

Samuel Kalu ati Victor Osinmhem lo gbeja ikọ Super Eagles, ti wọn si gba bọọlu meji sinu awọn Ikọ Benin Republic lati kẹsẹjari ninu ifẹsẹwọnsẹ naa.

Amọ awọn eniyan lori Twitter bere si ni rẹrin ni lẹyin ti ẹni to sọrọ nipa bi bọọlu ṣe n lọ(commentataor) ṣe aṣiṣe pẹlu bi o ṣe sọ pe Alex Iwobi n gba bọọlu ni Arsenal.

Ọrọ rẹ to tun pa awọn eeyan ni ẹrin ni bi o ti sọ pe ikọ Super Eagles ni ami ayo meji, nigba ti ikọ Naijiria ni ami ayo kan.

Ṣugbọn o pada tọrọ aforiji fun aṣiṣe naa.