Wole Soyinka: Ohun ìtìjú ni fún Naijiria bíí ìjọba se ti Sowore mólé

Ọjọgbọn Wole Soyinka ti kesi ijọba apapọ lati fi Omoyele Sowore silẹ, ki itiju to n ba orilẹede Naijiria ba le dinku.

Ninu atẹjade kan ti Wole Soyinka fi lede fun awọn akọroyin lo ti kesi ijọba apapọ bẹẹ.

O ni ko ba ofin mu bi wọn se tii Sowore mọle, ti Ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS si kọ lati fi silẹ nitori pe Sowore n pe fun atunto Naijiria lọna to ba ofin mu.

Bakan naa ni Soyinka tun bu ẹnu atẹ lu bi awọn osisẹ ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS se da ibọn bolẹ lati le awọn afẹhọnu han ka nilu Abuja lọ̀jọ Isegun.

Ọpọlọpọ awọn eniyan lo ti bu ẹnu atẹ lu bii ijọba se fi Ọmọyẹle Sowore si atimọle ni Olu ile isẹ Ajọ DSS ni ilu Abuja.