You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Makinde vs Adelabu: Olùdíje APC ní àkọsílẹ̀ àyànmọ́ òun nínú ìtàn Oyo kò gbọdọ̀ yẹ̀
Oludije fun ipo gomina nipinlẹ Ọyọ labẹ asia ẹgbẹ oselu APC, Adebayọ Adelabu ti sọrọ fun igba akọkọ lẹyin ti ile ẹjọ Kotẹmilọrun gbe idajọ rẹ kalẹ lọjọ Aje.
Adelabu, loju opo ikansiraẹni Facebook rẹ kede pe akọsilẹ ayanmọ oun ninu itan ipinlẹ Ọyọ ko gbọdọ tase, ni oun se pinnu lati mase jami lori ẹjọ naa.
O ni lọwọlọwọ bayii, oun ti gbe ẹhonu oun lori ibo gomina naa lọ sile ẹjọ to ga julọ nilẹ wa lati ba wọn da si lẹyin ti ile ẹjọ Kotẹmilọrun ti kede pe igbimọ olugbẹjọ awuyewuye ibo naa ko fun oun lanfaani to lati sọ tẹnu oun.
"Idajọ ileejọ Kotẹmilọrun yii lo tun sọ ireti mi ji pada ninu ilana eto idibo ati ẹka eto idajọ ninu igbesẹ wa lati ni akọọlẹ ninu itan."
Adelabu fikun pe nigba ti ẹgbẹ oselu APC fa oun kalẹ gẹgẹ bi oludije fun ẹgbẹ naa, wọn mọ pe oun ni oludije to dantọ julọ laarin ọpọ oludije to yọju lati wa du ipo naa, ti oun si sisẹ kara kara lati safihan akọsilẹ ipinnu ti oun ni lati se atunto awọn ohun alumọọni to wa nipinlẹ Ọyọ.
Oludije fẹgbẹ APC nipinlẹ Ọyọ naa ni, o wa ni akọsilẹ pe oun seto ipolongo ibo nibamu pẹlu awọn erongba oun fun ipinlẹ Ọyọ, to si da awọn eeyan ipinlẹ naa loju pe oun kaato lati sisẹ naa, idi si niyi ti wọn se dibo rẹpẹtẹ fun oun .
"Amọ awọn iransẹ okunkun pinnu lati ji asẹ tawọn eeyan ipinlẹ Ọyọ gbe le mi lọwọ lati dari wọn, idi si niyi ti mo se pinnu lati lọ sile ẹjọ ki n lee se ayipada igbesẹ ti ko tọ naa."
Adelabu fikun pe "nibayi ti ile ẹjọ Kotẹmilọrun ti se ayipada ohun ti ko dara naa si rere, mo rọ awọn eeyan ipinlẹ Ọyọ lati gba laafia laaye, ki wọn si maa ba isẹ to ba ofin mu ti wọn n se lọ nibayi ti a n lọ sile ẹjọ Kotẹmilọrun lati gba isẹgun wa."
Adelabu wa kadi ọrọ rẹ nilẹ pe lẹyin okunkun imọlẹ yoo tan, ko si bo ti wu ko pẹ to, ti oorun ba ti n yọ, isẹgun daju fun oun ati awọn eeyan ipinlẹ Ọyọ.