Hate Speech: Àwọn ọmọ Nàìjíríà ní kí ìjọba lọ wá'bi jókòó sí lórí àbádòfin ọ̀rọ̀ ìkóríra

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Lẹyin ti ile aṣofin agba l'Abuja gun le abadofin ti yoo fiya jẹ ẹnikẹni to ba ṣo ọrọ ikorira, awọn ọmọ Naijiria ti n fi erongba lede lori abadofin ọhun.

Ọpọlọpọ awọn ọmọ Naijiria lo fi aidunnu wọn han lori itakun ayelujara, pe abadofin naa ku diẹ kaato.

Femi Fani-Kayode to jẹ minisita fun ọrọ ọkọ ofurufu tẹlẹ ri sọ pe, abadofin naa jẹ ọna lati pa awọn ọmọ Naijiria lẹnumọ ni.

O ni "Ẹyin ọmọ Naijiria. Ẹ ma ṣatililẹyin fun abadofin yii o, to ba lee di ofin, ẹ ko ni lanfani lati sọrọ bo ṣe wu yin mọ."

Reno Omokri naa bu ẹnu atẹ lu abadofin ọhun loju opo Twitter, o ni, "ijọba to gori alefa latari itakun ayelujara wa fẹ maa gbogun ti awọn eeyan lori itakun ayelujara."

Awọn ọmọ Naijiria mii fẹnun tabuku abadofin naa loju opo Twitter.

Wọn sọ pe, ti ijọba ba le ṣamojuto eto ilera ati ọrọ abo, ko si ẹni ti yoo raye lati sọrọ kobakungbe si ijọba.

Ẹ wo awọn ohun ti awọn ọmọ Naijiria miran tun n sọ lori abadofin yii.