Arsenal vs Burnley: Kí ló kàn fún Arsenal báyìí lẹ́yìn tí Burnley yẹ̀yẹ́ wọn mọ́lé ní Emirates?

Ọkan lara adilemu fun ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal, Kieran Tierney ti sọ pe o yẹ kawọn ololufẹ ikọ agbabọọlu naa yẹyẹ wọn gẹgẹ bi wọn ti ṣe lẹyin ti Burnley lu wọn mọle pẹlu ami ayo kan sodo ninu idije Premier League lọjọ Aiku.

O buru debi wi pe balogun Arsenal, Pierre-Emerick Aubameyang gan an lo ṣeeṣi gba goolu kan ṣoṣo tiu Burnley fi bori wọlẹ Arsenal.

Ni bayii, Arsenal ti fidi rẹmi ninu meje ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹwaa ti wọn ti gba bayii.

Ẹgbẹrun meji ololufẹ ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal to wo ere bọọlu naa lo fi aidunnu wọn han sawọn agbabọọlu ati akọnimọọgba wọn, Mikel Arteta lẹyin ifẹsẹwọnsẹ naa.

Tierney sọ lẹyin ifẹsẹwọnsẹ naa pe igbiyanju awọn agbabọọlu Arsenal lori papa kudiẹ kaato.

Igba akọkọ ree ti Arsenal yoo fidi rẹmi ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹrin lera lera nile wọn lati bii ọdun mọkanlelọgọta.

Pẹlu bi wọn ti bori ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹrin ninu mejila ti wọn ti gba a, o ti pe ọdun marunlelogoji bayii ti ibẹrẹ saa bọọlu tuntun ti buru jai fun Arsenal bayii.

Goolu mẹwaa ti wọn gba sawọn ninu ifẹsẹwọnsẹ mejila ti wọn ti gba ni saa bọọlu yii lo kere julọ fun Arsenal lati ọdun 1982.

Lati oṣu kejila ọdun 2019 ti Arteta ti di akọnimọọgba Arsenal, awọn agbabọọlu rẹ ti kaadi pupa mẹfa.

Iwa aibikita bẹẹ naa lo mi ki Granit Xhaka gba kaadi pupa ti wọn fi le danu ninu ifẹsẹwọnsẹ ọjọ Aiku lẹyin to fẹ fun agbabọọlu Burnley, Ashley Westwood lọrun.