Real Madrid: Kí ni ká ti pe ìfarapa gbogbo ìgbàa Eden Hazard lórí pápá?

Eden Hazard agbabọọlu ọmọ Belgium to n ṣoju ẹgbẹ Real Madrid ti tun farapa lori papa iṣere.

Iṣẹlẹ yi waye lasiko ti Real Madrid n koju Alaves eyi ti wọn ti fidi rẹmi pẹlu goolu meji sookan.

Hazard to ṣe wi pe o ṣẹṣẹ kopa ninu ifẹwọnsẹ mẹta pere lati igba ti saa bọọlu ọdun yi ti bẹrẹ ko lo ju iṣẹju mejidinlọgbọn lọ lori papa ki wọn to gbe e jade.

A ko ti le sọ ni pato ẹya ara to da wahala tuntun yi silẹ fun botilẹ jẹ pe awọn kan ni kokosẹ rẹ ni.

"Mi o le ṣalaye nkan to ṣẹlẹ lalẹ oni. Tibi tire ni nkan to ṣẹlẹ si wa''

''Nipa Eden mo lero pe, mo si ni igbagbọ pe kii ṣe nkankan to lagbara pupọ. O sọ fun mi pe ki ṣe nkan to le. Mo lero pe ko ni ju bẹẹ lọ''

Ọrọ ti akọnimọọgba Madrid Zinedine Zidane sọ re lẹyin ifẹsẹwọnsẹ wọn.

Goolu ti Lucas Perez jẹ nipa gbe e silẹ gba a sile ni iṣẹju karun abala kini ni ikọ Alaves fi lewaju ninu ifẹsẹwọnsẹ naa.

Joselu naa da kun iya fun Real Madrid lẹyin aṣiṣe asọle Madrid Thibaut Courtois.

Casemiro lo pada wa jẹ goolu dondo fun Madrid ni nkan bii iṣẹju diẹ ti ifẹsẹwọnsẹ naa yoo fi pari.

Kini ka ti pe ifarapa gbogbo igba yii?

Ọdun 2019 ni Real Madrid na owo to le ni aadọjọ miliọnu poun lati ra Eden Hazard lọdọ Chelsea.

Lati igba to ti de si ẹgbẹ agbabọọlu naa igba mẹtadinlọgbọn pere lo ṣeṣe gba bọọlu fun ikọ Zinedine Zidane.

Nibẹrẹ saa bọọlu yi, ko ribi kopa nitori pe o farapa lori ẹsẹ ọtun rẹ ti o si fagidi gba nigba mẹta pere ki o to ko arun Covid-19 nibẹrẹ oṣu Kọkanla