You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ajibade Babalade: Àwọn ọmọ Naijiria ṣèdárò gbajúgbajù agbábọ́ọ̀lù Super Eagles tó dolóògbè
Awọn ọmọ Naijiria ti n ṣedaro gbajugbaja agbabọọlu Naijiria, Ajibade Babalade to se alaisi ni ẹni ọdun mejidinlaadọta.
Babalade to kopa ninu idije Africa Cup of Nations ni ọdun 1992, lo ku lojiji lẹyin ti o ni aisan ọkan.
Akẹgbẹ rẹ, Ike Shorunmu ni ileewosan akọkọ ti wọn gbe e lọ kọ ọ, ko to di wi pe wọn gbe lọ si ileewọsan ẹkọni ti ilu Ibadan, tii o si dakẹ ki wọn to wọle sinu ileewosan naa.
Ajọ to n risi ọrọ erebọọlu ni Naijiria. NFF lasiko ti wọn n ṣedaro agbabọọlu ọwọ ẹyin to doloogbe naa loju opo Twitter wọn, sọ wi pe ibanujẹ ni iroyin iku rẹ jẹ fun awọn.
Awọn ololufẹ rẹ ranti iṣẹ takuntakun to ṣe lati gba ami ẹyẹ lasiko idije Afcon 1992 to waye ni orilẹede Senegal.
Arakunrin Nasiru Suleiman ni Babalade ni laipẹ ki o to ku ni o ṣi fẹran aworan ti oun fi sita nigba ti oun ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi ọmọ rẹ akọkọ.
Bakan naa ni awọn ololufẹ erebọọlu ni Naijiria fikun wi pe ipa takuntakun ti Babalade ko ninu ẹgbẹ agbọọla Enyinba lo jẹ ki wọn gba ami ẹyẹ CAF Champions League nigba rẹ.
- Owó oúnjẹ ni mo lọ ọ gbà, oyún ọmọ tí mo jù sí àkìtàn ni mó gbé wálé- Dupe, ìyá Muiz
- Ènìyàn 156 míràn ló tún kó Coronavirus ní Nàìjíríà ní ọjọ́ Ẹtì
- Olórin Kano tí wọ́n dájọ́ ikú fún pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn
- Nàìjíríà làwọn ní ìfẹ́ sí ìpèsè abẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19 tí Russia ṣe
- Wo ọ̀nà ìsanwó tuntun fún àwọn oníbárà iná mọ̀nàmọ́ná ní Eko (EKDC)
- Àwọn dókítà yóò bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódí lọ́jọ́ Ajé
Iyawo Ajibade Babalade ati ọmọ rẹ mẹta ti wọn n gbe lorilẹ-ede Amerika lo gbẹyin rẹ.
Ni Igba aye rẹ, Babajide Shorunmuti jẹ akọnimọọgba fun ẹgbẹ agbabọọlu Niajiria, Shooting Stars.
Bakan naa lo gba bọọlu loke okun fun awọn orilẹ-ede bii Ivory Coast (African Sports0 , Korea (Anyang LG Cheetahs), Austria (SK Sturm Graz) ati ẹgbẹ agbabọlu Mohun Bagan AC ni orilẹ-ede India.