Russia Covid 19 Vaccine: Nàìjíríà ṣetán àjọṣepọ̀ pẹ̀lú Russia lórí ìpèsè abẹ́rẹ́ àjẹsára

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Ijọba orile-ede Naijiria ti fifẹ han lati ṣe amulo abẹrẹ ajẹsara Sputnik V ti orile-ede Russia n ṣeto lati koju arun Covid -19.

Lasiko ipade kan ti awọn alaṣẹ ileeṣẹ to n mojuto eto ilera Naijiria ṣe pẹlu aṣoju ilẹ Aṣoju Russia si Naijiria ni ọrọ yii ti jẹyọ.

Ninu ipade yi ni Minisita feto ilera Dokita Osagie Ehanire wa pẹlu Alexey L. Shebarshin lati Russia.

Gẹgẹ bi ohun ti ileeṣẹ ilera fi soju opo Twiter wọn, ''Naijiria n wa gbogbo imọ nipa itọju ati abẹrẹ ajesara lati koju arun yii''

Ileeṣẹ naa tun sọ pe awọn nifẹ si ibaṣepọ pẹlu Russia eyi ti yoo mu ajọsepo to gunrege wa.

Adebimpe Adebiyi to jẹ ọga ẹka ile iwosan ileeṣẹ ilera sọ pe anfaani nla re fun Naijiria lati fikun agbara ipese abẹrẹ ajẹsara wọn.

Ninu awọn ohun ta ri ka loju opo Twitter wọn, ileeṣẹ ilera ko sọ pato boya awọn ti gba abẹrẹ ajẹsara ti wọn n pe orukọ rẹ nui Sputnik lọwọ Russia.