Chelsea: Chelsea dun DJ Cuppy nínú lẹ̀yìn tí Arsenal gba omijé lójú rẹ̀

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Akọda oro koda bi bi ada gbẹyin ni Yoruba maa n wi. Bẹẹ gan an lọrọ ri fun ẹgbẹ agbabọọlu Aston Villa to kọ lẹta si iya lọwọ Chelsea.

Aston Villa lo kọkọ gba goolu sawọn Chelsea ninu ifẹsẹwọnsẹ ọhun.

Ṣugbọn Chelsea fi ye wọn pe agbo to tadi mẹyin, agbara lo lọ mu wa ni abala keji ere bọọlu naa.

Christian Pulisic lo kọkọ dayo naa pada nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa di wakati kan.

Lẹyin iṣẹju meji pere si igba naa ni ẹlẹsẹ ayo Olivier Giroud fi ọba le fun Chelsea eyi ti o mu Chelsea siwaju pẹlu ayo meji sodo.

Awọn kan tiẹ sọ pe ẹbun ayẹyẹ ọjọ ibi ni awọn agbabọọlu Chelsea fi ijaweolubori ninu ere bọọlu naa ṣe fun akọnimọọgba wọn Frank lampard to pe ọdun mejilelogoji lọjọ Abaméta.

Ẹwẹ, lẹyin ti Florence Otedola ti ọpọ mọ si Chelsea DJ kọ Arsenal silẹ pẹlu omije loju, o ti kede loju opo Twitter rẹ pe oun fẹran ohun ti oun ri lara ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea.

Amọ o ṣalaye pe oun si ni lati wo awọn ẹgbẹ agbabọọlu mi ki oun to pinu eyi ti oun maa darapọ mọ.