You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Coronavirus: Borussia Dortmund fẹ̀yìn Schalke 04 gbolẹ̀ bí Líìgì ilẹ̀ Germany ṣe padà bẹ̀rẹ̀
Ayo mẹrin si odo ni ikọ Borussia Dortmund fi gbo ewuro soju ẹgbẹ agbagbọọlu Schalke 04 bi idije Bundesliga ṣe pada gberasọ lọjọ Abamẹte, ọjọ kẹrindinlogun oṣu karun un ọdun 2020.
Erling Braut Haaland lo kọkọ rẹyin awọn ikọ Schalke ni iṣẹju kọkandinlọgbọn ti ifẹsẹwọnsẹ ọhun bẹrẹ.
Ko pẹ si ti Raphaël Guerreiro tun sọ bọọlu sinu awọn Schalke, lẹyin naa lo sọ goolu miran wọle ni abala keji ifẹsẹwọnṣe ọhun.
Thorgan Hazard naa ko gbẹyin rara nigba to ṣe bi ọkunrin laarin iṣẹju diẹ ninu abala keji ifẹsẹwọnsẹ naa.
Ifẹsẹwọnsẹ naa waye laisi ero iworan.
Bundesliga ni Liigi akọkọ nilẹ Yuroopu ti yoo bẹrẹ idije bọọlu lẹyin ti ajakalẹ arun Covid-19 mu ki ere idaraya kogba wọle kaakiri agbaye ni ibẹrẹ ọdun 2020.
Mikel Obi fi ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù rẹ̀ sílẹ̀ ní Turkey nítorí coronavirus
Balogun ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria nigba kan, to tun jẹ agbabọọlu Chelsea tẹlẹ, John Mikel Obi ti finu-findọ fi idije Turkish Super Lig leaders Trabzonspor, silẹ lẹyin ọjọ diẹ to fi ero ọkan rẹ han si bi liigi naa ṣe n tẹsiwaju lai fi itankalẹ arun coronavirus ṣe.
Liigi naa jẹ ọkan lara awọn idije bọọlu l'agbaye to ṣi n waye, botilẹjẹ pe wọn ko ṣe ni gbangba.
Ṣugbọn ni ọjọ Abamẹta to kọja, Obi, to jẹ ọkan pataki ninu idije Trabzonspor, kọ ọ si ori ayelujara pe oun ko faramọ igbesẹ naa.
- Paul Pogba gbé ètò owó dídá kalẹ̀ fún ààrùn Coronavirus
- Wọ́n ti wọ́gilé ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ Arsenal àti Brighton lẹ́yìn tí Mikel Arteta lùgbàdì àrùn Coronavirus
- Àyẹ̀wò gbogbo irinṣẹ́ ètò ìlera ti di dandan báyìí lẹ́yìn ikú Chineme Martins- NFF
- Láì lo Kakulétọ̀, mo ní ọpọlọ ìṣirò, tábìlì ìṣirò wà lórí mi - Human Calculator
Ọjọ Iṣẹgun ni ẹgbẹ agbabọọlu rẹ fi ikede sita pe o ti fi opin si adehun iṣẹ to wa laarin wọn, lai boju wo owo ti yoo padanu.
Obi kọ si oju opo ayelujara Instagram rẹ pe "awọn nkan miran to ṣe iyebiye ju bọọlu gbigba wa l'aye. Ara a mi ko gba a, mi o si fẹ ẹ gba bọọlu niru ipo bayii."
"O yẹ ki gbogbo eniyan o wa nile pẹlu idile wọn ati awọn ẹbi niru asiko yii. Ki wọn o wọgile saa yii, pẹlu bi agbaye ṣe n dojukọ asiko ewu bi eyi."
Awọn agbabọọlu miran to n gbe l'orilẹ-ede Turkey bi i Radamel Falcao ati Didier Drogba f'esi si ọrọ naa pe bẹ ẹ gan lo ṣe yẹ ko ri.
O ku ọjọ kan ki ẹgbẹ agbabọọlu Mikel, Trabzonspor o koju Istanbul Basaksehir ni Obi fi ọrọ naa sita.
Eniyan mẹfa pere lo ni arun coronavirus lasiko ti Obi fi ikede naa sita, ṣugbọn o ti pe mẹtadinlaadọta bayii.
Ijọba si ti gbe igbesẹ lati fi opin si itankalẹ rẹ ku, nipa titi awọn ileewe ati fasiti, ti wọn si n fi aaye gba awọn idije ere idaraya lai si awọn oluworan nibẹ. Ko si tun si irinajo oju ofurufu lọ si awọn orilẹ-ede kan mọ.