You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Emmanuel Adebayor: Agbábọ́ọ̀lù Togo rántí ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé lásìkò AFCON 2010
Ọjọ buruku eṣu gbomi mu, oni ọjọ kẹjọ oṣu kinni ọdun 2020 lo pe ọdun mẹwaa tawọn agbebọn kan kọlu awọn agbabọọlu ilẹ Afirika lorilẹede Angola.
Awọn ti ori ko yọ ninu iṣẹlẹ naa, ninu eyi tawọn kan ti di ero ọrun, ṣe iranti bi iṣẹlẹ ọhun ti ṣẹlẹ lapa ẹkun Cabinda lorilẹede Angola.
Akọroyin BBC, Matthew Kenyon naa ṣe iranti bi ikọlu naa ṣe mu ẹmi awọn agbabọọlu orilẹede Togo meji lọ.
- Siasia bẹ̀bẹ̀ ìrànwọ́ N100m lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà láti ṣejọ́ jìbìtì tí FIFA fi kàn án
- Van Persie gbàgà lẹ́nu rẹ! Solskjaer fárígá lẹ́yìn tí Van Persie ló ń rẹ́rìn-ín
- Gómìnà mẹ́ta àtí ènìyàn 1,242 ló kó sí panpẹ EFCC ni ọdún 2019
- Ṣo mọ̀ pé J.F Odunjo jẹ aṣòfin àti mínísítà nílẹ̀ yìí, yàtọ̀ sí pé ó jẹ́ òǹkọ̀wé?
- Ikú òjijì kò jìnnà àmọ́ ọ̀nà méje rèé láti dènà rẹ̀
Kenyon ni lẹyin tawọn agbebọn kọlu ọkọ tawọn ẹgbẹ agbabọọlu Togo wa ninu rẹ, loun ṣe ifọrọwanilẹnuwo pẹlu agbẹnusọ ikọ naa, tii ṣe Emmanuel Adebayor, to n ṣoju ikọ agbabọọlu Manchester City nigba naa.
O ṣalaye pe, ti ibẹru-bojo ni Adebayor fi n sọ ohun to sẹlẹ ṣawọn agbabọọlu Togo, koda Adebayor sọ ninu ifọrọwanilẹnuwo naa pe, ẹru ṣi n ba oun lẹyin tawọn akẹgbẹ rẹ meji ṣagbako iku ninu ikọlu naa.
Junior Senaya to jẹ ọkan lara awọn agbabọọlu fikun ọrọ Adebayor pe, ninu ọkọ lawọn wa tawọn n gbọ orin, ṣadeedee lawọn bẹrẹ si ni gbọ iro ibọn ninu igbo.
''Ka to wi, ka to fọ, wọn yinbọn pawọn akẹgbẹ wa ti a jọ wa ninu ọkọ, nibi ti gbogbo wa ti mọ pe ewu n bẹ loko longẹ niyẹn,'' Senaya lo woye bẹẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Kodjovi Obilale, to jẹ aṣọle nigba naa kan ṣadeedee ri pe oun ti fara gbọta, loju ẹsẹ lo rii pe ẹjẹ bẹrẹ si ni da lati ikun ati ẹsẹ oun mejeeji.
Obiulale ni lẹsẹkẹsẹ loun bẹrẹ si ni ke pe ''ẹ gbami, ẹ gbami, ọta ibọn ti ba mi, mo fẹ ri ọmọbinrin ati ọmọkunrin mi, mi o fẹ ku sibi.''
Igbakeji akọnimọọgba fẹgbẹ agbabọọlu Togo, Amelete Abalo naa figbe ta pe ọta ibọn ba oun, Amelete pada ku lẹyin ti ọta ibọn ba a tan.
Adebayor ranti pe, fun bi ọgbọn iṣẹju lawọn janduku naa fi n dabọn bo ọkọ tawọn wa ninu rẹ, lai le kuro loju kan naa.
Adebayor ni iṣẹlẹ naa jẹ ọkan lara awọn manigbagbe iṣẹlẹ to buru ju to ṣẹlẹ s'oun laye.