Alexis Sanchez lóun kò kabamọ ìgbà tóun ló ní Man United

Atamatase Alexis Sanchez, ni toun ti bi oun ko ti ṣe raye gba lori papa fun Manchester United to bi o ti ṣe wu oun,oun ko kabamọ pe oun darapọ mọ ẹgbẹ naa.

Ọmọ orileede Chile naa darapọ mọ Inter Milan fun saa ọdun kan lẹyin to lo oṣu mọkandilogun ni Old Trafford.

Nigba to wa ni Man United, oun ni agbabọọlu to n gba owo ju lọ tii ṣe £400,000 lọsẹ.

Ṣugbọn goolu marun un pere lo jẹ ninu ifẹsẹwọnsẹ marundinlaadọta to kopa ninu rẹ lati igba to de sọdọ wọn lati Arsenal loṣu Kini ọdun 2018.

''Inu mi dun pe mo lọ si Manchester United.Mi o ṣẹṣẹ ma s pe oun ni ẹgbẹ to ti gba ami ẹyẹ julọ ni ilẹ Gẹẹsi''

O salaye pe nigba ti oun lọ si Arsenal,o dun mọ oun ṣugbọn United n gboro si lasiko naa ti wọn si n ra awọn agbabọọlu tori pe wọn fẹ pegede.

''Mo fẹ darapọ mọ wọn lati gbogbo ife.Mi o kabamọ pe mọ lọ si ọdọ wọn''

Goolu ọgọrin(80) ni Sanchez jẹ ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹ́rìndínláàdọ́sàn án (166) ni Arsenal lẹyin to buwọlu iwe adehun miliọnu ọgbọn poun lati Barcelona lọdun 2014.

O gba ami ẹyẹ agbabọọlu to pegede julọ ldun 2017 ni Premiership.

Amọ lati igba tokuro ni Arsenal lọ si Man United ni nnkan to ti rọgbọ mọ.

Goolu meji pere lo jẹ ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹtadinlọgbọn ni saa to kọja botile j wi pe o ṣe daada forileede Chile ninu idije Copa Amerika to ti jẹ goolu meji.