Transfer Window: Èrò olólùfẹ́ eré bọ́ọ̀lù ṣọ̀ọ̀tọ̀tọ̀ lórí Iwobi, Lukaku àti Luiz

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Agbabọọlu Arsenal to jẹ ọmọ Naijiria, Alex Iwobi wa lara awọn agbabọọlu to darapọ mọ ẹgbẹ agbabọọlu miiran l'Ọjọbọ to jẹ gbedeke ọjọ ti ẹnikẹni le ra agbabọọlu tuntun ṣaaju saa bọọlu mii to bẹrẹ lonii ọjọ Ẹti nilẹ Gẹeṣi.

Iwobi fọwọsi adehun ọdun marun un pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu Everton lẹyin ti wọn san miliọnu mejidinlọgbọn owo pọun fun Arsenal.

O tun wa ninu adehun pe Everton yoo pada fi miliọnu meje kun owo naa to ba ya.

Akọnimọọgba Arsenal Unai Emery ni Iwobi ṣiṣẹ takuntakun nigba to fi wa pẹlu ikọ Arsenal.

Emery ṣapejuwe Iwobi gẹgẹ bi awokọsẹ rere fawọn ọjẹwẹwẹ agbabọọlu, bẹẹ lo gbadura fun un wi pe yoo ṣoriire nibi to n lọ

Bi Iwobi ṣe fi Arsenal silẹ lọ Everton jẹ ibanujẹ fun ọpọlọpọ ololufẹ rẹ, ko da aworan ẹni tomi n bọ loju rẹ lọpọ wọn ṣapejuwe bi ọrọ naa ṣe dun wọn to.

Ohun to kọju sẹnikan, ẹyin lo kọ sẹlomiiran, nibi tawọn ti n sunkun pe Iwobi lọ, lawọn kan ti n yọ pe Iwobi kuro ni Arsenal.

Awọn kan tiẹ nifẹ Iwobi ṣugbọn awọn ko fẹ wa lara awọn agbabọọlu Arsenal mọ.

Igba kan n lọ, igba kan n bọ, bi Iwobi ṣe fi Arsenal silẹ bẹẹ naa ni David Luiz gbera pa lati Chelsea wa si Arsenal.

Luiz kọwọ bọwe adehunọlọdun meji pẹlu Arsenal lẹyin ti Arsenal san miliọnu mẹjọ owo pọun.

Lẹyin ọ rẹyin, ẹlẹsẹ ayo, Romelu Lukaku fi ẹgbẹ agbabọọlu silẹ lọ ikọ agbabọọlu Inter Milan.

Lukaku wa lara awọn agbabọọlu ti Man U ko lo daadaa mọ ni saa bọọlu to lọ, Marcos Rashford lo maa n saa ba gba aye rẹ.

Ẹwẹ, lọkunrin lobinrin lawọn ololufẹ Inter Milan tu jade lati ki Lukaku kaabọ si ikọ agbabọọlu wọn l'Ọjọbọ.